propeller

Propellerads

Monday, 16 January 2017

E Wo Bi Ijamba Moto Se Awon Mejeeji Yi Di Oko ati Iyawo. Igbeyin Ife Won Yoo Ya Yin Lenu

Arakunrin kan ati Obinrin kan ni won ni ijamba moto.
Ijamba yi waye latari iwakuwa obinrin naa latari aiti dangajia re nipa oko wiwa.
Oko mejeeji naa baje doju ami debi wi pe ko see tunse
Iyalenu ibe ni wi pe bi ijamba naa se po to ti awon oko naa baje to, 
ifarapa ranpe ti o to nkan lo se awon mejeeji.
Koda awon mejeeji lo jade ninu oko naa funra won.
Leyin ti won jade ninu oko tan, Obinrin naa lo koko soro.
O wi bayii wi pe:
Abi e o ri nnkan bi, se wi pe okunrin ni e, emi si je obinrin, Olorun o ma tobi oo
Wo bi ijamba yii se buruto, ifarapa tintin yii lo jo ba wa,
Eyi toka ami wi pe Olorun fe ka fi eleyii pade ka si jo maa gbe papo pelu alaafia titi aye wa ni
Ijamba yii si ti ko aburu ibi igbeyawo wa lo niyen.
Lai sose tabi wo oro naa leemeji, Okunrin naa fesi wi pe:
Beeni apeere nla ni aifarapa wa yii je fun wa lati odo Olorun. Nipa idi eyi mo faramo lati fi e se aya.

Obinrin naa te siwaju:
Tu wo o, bi oko mi se baje to ti gbogbo nnkan inu re se baje to.
Oti bia (beer) yii nikan ni ko fo ti ko si danu.
Iyen ni pe Olorun fe ka mu oti yii, ka le fi se isami ife wa, Haa Olorun ma tobi oo
Arabinrin naa gbe oti naa, o si mu le okunrin naa lowo.
 O wi pe: Oloolufe mi tuntun, gba ki o si, ki a si mu lati fi ife wa han.

Lai sose, Arakunrin naa si oti naa, o si daa senu, o mu u de idaji
o gbe aabo toku fun arabinrin naa ki oun naa mu
Gbigba ti arabinrin naa gba oti naa, dipo ko mu,
nise lo mu ideri igo naa ti o si fi di enu igo oti naa, o si daapada fun okunrin naa

Eyi ya arakunrin naa lenu, o si bere wi pe:
Ololufe mi kilo de ti oofi mu ninu isami ife wa

Arabinrin naa fesi wi pe:
Ko nilo ki emi mu mo nitori mo ti te ateranse si awon Olopa lati wa mu arakunrin to mu oti yo to si fa ijamba oko fun mi. Ti emi naa ba mu oti yi a je wi pe awa mejeeji ni won yoo mu. Nipa idi eyi je ki olopa rora de ki won si wa mu e lo nitori o ti wa oko nigba ti o ti mu oti to si lodi si ofin irinan.

Haaaaaaaaa, Obinrin pelu ete.
Aadama tun ti je eso
Ojo wo leyin okunrin maa tobori ete obininm

Itan aroso lasan ni eyi ti a se eda ra lati owo Adeleke Ahmed

Gbayi fun gbogbo ete Obinrin

Friday, 13 January 2017

Gbogbo Abiyamo Iku o ni Pa Awon Omo Wa oo, E wo Nnkan Merindinlogbon (26) Ti E o Gbodo Se Fun Omo Ikoko.

 A fi eyi se ikilo fun gbogbo abiyamo nipa bi won yoo se maa ba awon ikoko ati awon omo tuntun ati oponlo lo. Bo tile je wi pe ede geesi ni won fi se atoka awon aworan naa, sugbon a ni igbagbo wi pe aworan naa le salaye ara re lai tuu. Eyin naa e se agbeyewo awon aworan naa.







 

 A lero wi pe e ti ri eko kan tabi omiran dimu
Ju gbogbo re lo.
Gbayiii fun gbogbo Abiyamo

E Tun Wo Ona Ti Awon Iyawo Ile Fe Fi Maa Fi Iya Je Awon Oko Won. Eyin Okùnrin E Yaa Mura o


Arabinrin kan lo lo ra ohun elo ile ni ile itaja igbalode. Nigba to raja tan to fe san owo, o si apamowo re, ni olutaja wa se akiyesi ero iyipada amohunmaworan (T.V Remote) ninu apamowo re. Olutaja naa ko le mu oro naa mora, o si bere bi lowo arabinrin naa pe"Ki lo wa de ti e fi di ero iyipada amohumaworan (TVRemote) jade? to ba je lati ra omiran ni baale yin lo ye ko je"
Arabinrin naa dahun wi pe: Tori baale mi yen gan naa ni mo se mu jade. Mo ni ko sinmi jade kajo wa ra nnkan ni sugbon o ni oun fe wo boolu afesegba. Iyen ni pe boolu pataki ju emi naa lo. Mo yaa dogbon mu rimuutu jade, ko ma le ri wo.
 *Eko nla leyi je fun eyin okunrin lati ma se gbagbe lati maa ke iyawo ni gbogbo ona ki e si ma fi ife boolu bori tiwon.

Oro ko pari sibe ooo... Olutaja naa rerin o si se oja arabinrin naa. sugbon iyalenu lo je fun arabinrin yii nigba ti olutaja naa so fun wi pe oko re ti dina kaadi ti o mu jade lati fi san owo oja ti o ra. Iyen ni pe, oun mu rimuutu, oko naa si dina oja re naa ni rira. meji ti pin merin.
*Eko ibe ni pe obinrin lo ni ete okunrin lo si ni ogbon. Bowo fun eto oko re ni igba gbogbo

Itan naa koi tan oo... Bi oko mi ba mo ayinike, emi naa mo ayinipada ni esi ti arabinrin naa wi. O towo bo inu apamowo re o fa kaadi ti oko re jade. Nitori aibamo naa ni mo se mu kaadi tire naa dani tele, sugbon ni bayii, kaadi re ni maa fi ra gbogbo nnkan. O seni laanu wi pe arakunrin naa ko ranti ti kaadi tire. Oro di gobe
*Eko ta ri ko ninu eyi ni pe: Ma se foju di ete Iyawo re. Ete obinrin lagbara ju bi o ti lero lo.

Ko tan sibe yen... Bi arabinrin yii se fi kaadi oko re si enu ero isanwo, o te iye to fe san, ero isanwo naa ba so wi pe TE AWON NUMBA TI A FI RANSE SI ORI ERO IBANISORO RE SIBI. Haaaa, Iru adanwo wo tun re.
*Eko: Ti iwo ba gbiyanju lati lo ete obinrin, Olorun mo bo se le gbe won nija

A si n te siwaju... Obìnrin náà rerin muse pe ori yo oko oun. sugbon lojiji ero ibanisoro kan dun ninu apamowo re bii igba ti atejise kan wole.o towo bo apamowo re ki o mu eo ibanisoro naa jade lo ba di ero ibanisoro oko re. Haaaa, mo ba se nkan lori foonu re lanaa,lo fi gbagbe re si mi lowo. Egberun saamu re ko le sa mo Olorun lowo. O te nomba, o si san owo.
*Eko: Olorun ma fawa le eni ma mu wa lowo. ori to ba maa je iko yo je saa ni

Idan si n lo... Nigba ti arabirin naa dele, ko ri oko ayokele re nile. Haaa kilode, nigba to wole lo ba iwe pelebe lori tabili ti oko re ko sile to lo bayi wi pe:  Mi o ri rimuutu, eyi lo je ki emi ati awon temi gbe oko re lo wo boolu naa ni ìgboro. O si ma to aago mesan aabo ale kin to de. Pemi sori aago to ba nilo nnkan kan. Ìgboro n dun".
*Eko nla: Okunrin o se di lowo agaaga nipa ariya.

Egbo tani oro naa maa dun ju.

Gbayii fún loko laya.

Tuesday, 10 January 2017

Iya Osogbo ko jale, o ni oun o sere tiata mo. Ohun to fa yoo ya yin lenu


Ogbontarigi osere tiata Grace Oyin Adejobi ti gbogbo wa mo si Iya Osogbo je aya osere agba ni Oloogbe Oyin Adejobi. Ninu iforowanilenuwo pelu iya naa ni o ti so idi re ti oun o se ni kopa ninu fiimu kankan mo. Iya agbalagba naa ti a bi ni odun 1931 ti se ere ori itage bo o ti le ni ogun odun seyin. Mama naa wa se alaye wi pe ti a ba wo ojo ori ohun, agba ti n de, ohun o si le ja lamba soke sodo lati ibudo ere ko si ibo mi mo bii ti igba kan. Laalaa kooko jan-an jan-an ara lo si n fi abo si. Isinmi lo ku fun oun gege bi agba ninu osere fiimu ni orile ede Naijiria.
   Iya Osogbo so bayii:
    Mi o kin se omode mo, mi o ni okun lati maa kaakiri lati oko kan si omiran, leyin iku oko mi mo ti kopa ninu fiimu to po ti mi o le kaa tan, sugbon ni bayii, mi o le se ere ibile wa mo latari wahala ati bi ofo ati epe to wa ninu re.

Awa gbaa ni adura wi pe ki Olorun tubo bawa lora emi Iya aafin Grace Oyin Adejobi (Iya Osogbo)
Lagbara Olorun ori eyin ololufe wa ko ni di ori eran iya osogbo oo

IYA OSOGBO 
GBAYIIIII

Monday, 9 January 2017

E WO OHUN TO SELE SI BABA YORUBA


Won se bi eye ku, won se bi eye lo,

Eye o ku ni se ni eye awodi lo re wu ye 
E ma lo ro wi pe eye ku.
Owe awon agba lo so wi pe agbo to tadi meyin agbara lo lo mu wa. O ti to ojo meloo kan ti e ti ri nnkan ka lati owo Emi omo yin, aburo yin, ore yin, ololufe yin BABA YORUBA.
Orisiirisii ateranse, ipe ati oro iwuri ni mo n gba yala lori ero ibanisoro, ori ayelujara, iwe oju ati ikanni Kilonsele(whatsapp). Eyi lo je ki inu mi dun wi pe haa, ase awon eniyan n feran mi. Mo dupe lowo awon ore mi to se iranti isele to sele simi ni ojo karun, osu kinni, odun 2016 nigba ti mo ni ijamba moto ni ilu eko. ojo naa re bi ana yii. Sugbon iku to ye ko pani to ba sini ni fila sonu ope lo ye wa. Lagbara Olorun, eyin naa ko ni te lowo oloore yin. 
Kii se pe ko wu mi lati le alemode sugbon, oke ibi ni ko je ka ri oke ohun. Sugbon ni bayi omi tuntun ti ru eja nla ti won ale odo. Lotun lotun le o ma ri mi wo bii iran. Laipe yii a oo se agbejade oju ewe ayelujara tiwa naa, yato si buloogi ti a n loyi. ti eyin naa yo si ni anfaani lati fi oro sori re. 
Ise n lo lowo
Haaaaaa, Eru maa ba won, Aya won maa ja, Won o ni duro woo tan, Eyin gan e mo mo pe ise naa
Gbayiii ni looto