Friday, 13 January 2017
E Tun Wo Ona Ti Awon Iyawo Ile Fe Fi Maa Fi Iya Je Awon Oko Won. Eyin Okùnrin E Yaa Mura o
Arabinrin kan lo lo ra ohun elo ile ni ile itaja igbalode. Nigba to raja tan to fe san owo, o si apamowo re, ni olutaja wa se akiyesi ero iyipada amohunmaworan (T.V Remote) ninu apamowo re. Olutaja naa ko le mu oro naa mora, o si bere bi lowo arabinrin naa pe"Ki lo wa de ti e fi di ero iyipada amohumaworan (TVRemote) jade? to ba je lati ra omiran ni baale yin lo ye ko je"
Arabinrin naa dahun wi pe: Tori baale mi yen gan naa ni mo se mu jade. Mo ni ko sinmi jade kajo wa ra nnkan ni sugbon o ni oun fe wo boolu afesegba. Iyen ni pe boolu pataki ju emi naa lo. Mo yaa dogbon mu rimuutu jade, ko ma le ri wo.
*Eko nla leyi je fun eyin okunrin lati ma se gbagbe lati maa ke iyawo ni gbogbo ona ki e si ma fi ife boolu bori tiwon.
Oro ko pari sibe ooo... Olutaja naa rerin o si se oja arabinrin naa. sugbon iyalenu lo je fun arabinrin yii nigba ti olutaja naa so fun wi pe oko re ti dina kaadi ti o mu jade lati fi san owo oja ti o ra. Iyen ni pe, oun mu rimuutu, oko naa si dina oja re naa ni rira. meji ti pin merin.
*Eko ibe ni pe obinrin lo ni ete okunrin lo si ni ogbon. Bowo fun eto oko re ni igba gbogbo
Itan naa koi tan oo... Bi oko mi ba mo ayinike, emi naa mo ayinipada ni esi ti arabinrin naa wi. O towo bo inu apamowo re o fa kaadi ti oko re jade. Nitori aibamo naa ni mo se mu kaadi tire naa dani tele, sugbon ni bayii, kaadi re ni maa fi ra gbogbo nnkan. O seni laanu wi pe arakunrin naa ko ranti ti kaadi tire. Oro di gobe
*Eko ta ri ko ninu eyi ni pe: Ma se foju di ete Iyawo re. Ete obinrin lagbara ju bi o ti lero lo.
Ko tan sibe yen... Bi arabinrin yii se fi kaadi oko re si enu ero isanwo, o te iye to fe san, ero isanwo naa ba so wi pe TE AWON NUMBA TI A FI RANSE SI ORI ERO IBANISORO RE SIBI. Haaaa, Iru adanwo wo tun re.
*Eko: Ti iwo ba gbiyanju lati lo ete obinrin, Olorun mo bo se le gbe won nija
A si n te siwaju... Obìnrin náà rerin muse pe ori yo oko oun. sugbon lojiji ero ibanisoro kan dun ninu apamowo re bii igba ti atejise kan wole.o towo bo apamowo re ki o mu eo ibanisoro naa jade lo ba di ero ibanisoro oko re. Haaaa, mo ba se nkan lori foonu re lanaa,lo fi gbagbe re si mi lowo. Egberun saamu re ko le sa mo Olorun lowo. O te nomba, o si san owo.
*Eko: Olorun ma fawa le eni ma mu wa lowo. ori to ba maa je iko yo je saa ni
Idan si n lo... Nigba ti arabirin naa dele, ko ri oko ayokele re nile. Haaa kilode, nigba to wole lo ba iwe pelebe lori tabili ti oko re ko sile to lo bayi wi pe: Mi o ri rimuutu, eyi lo je ki emi ati awon temi gbe oko re lo wo boolu naa ni ìgboro. O si ma to aago mesan aabo ale kin to de. Pemi sori aago to ba nilo nnkan kan. Ìgboro n dun".
*Eko nla: Okunrin o se di lowo agaaga nipa ariya.
Egbo tani oro naa maa dun ju.
Gbayii fún loko laya.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment