Ni ojo kini, osu kejila odun 2016 {01 / 12 / 2016} awon akekoo to sese pari ni ile eko ifafiti pelu ipo kini ti a mo si first class ti won si n sin ijoba labe NYSC lo jade laye lakata awon NYSC naa latari airi aisan ranpe ati airi itoju to peye ni aago idanilekoo {orientation camp}.
Oruko omobinri yii ni Ifedolapo Oladepo ti o wa ni ago idanileko agunbaniro ipinle Kano. Ifedolapo jade ni ifafiti nipa imo ero igbalode Ladoke Akintola (LAUTECH) ni Ogbomoso, o si jade pelu ipo kini ninu imo nipa igboke-gbodo irin ajo. Sugbon o seni laanu wi pe iku ko je ki arewa naa lo eto eko ati esi eko re naa pe nigba ti iku si ni owo ise leyin aisan ranpe to se ni aago idanilekoo NYSC. Iroyin kan so wi pe aibikita awon alakoso ago idanilekoo ati aini eto ilera to peye lo fa iku arabinrin naa. Ifedolapo ku si ile iwosan ni ojo kini osu kejila odun 2016 won si ti sin si ilu re ni Ogbomoso.
Ifedolapo oo, Sun re ooo.
Tako tabo la da ile aye, iku tun kuro ni ago idanileko NYSC ni Kano, o tun gba ipinle Zamfara lo, o fa akeko kunrin kan yo laarin awon egbe re o si mu lo. Haaa, ikunle abiyamo. Ukeme Asuquo Monday to je akekoo to sese jade pelu ipo kini naa tun ku. Ifura ni oogun agba gege bi owe awon agba. Gbara ti Ukeme ti ri wi pe Zamfara ni NYSC gbe oun lo ti n wa gbogbo ona lati ye irin ajo naa gege bi ore re ti se jabo iroyin naa lori oju iwe {facebook}. eyi ni ohun ti ore re te jade gege bi oro ti awon jo so gbeyin lori whatsapp
Haaa, gbogbo akekoo orile ede Naijiria, a bi e ti sun, Ooorun we niru akoko yi koo.
E ji giri ki a si kun fun adura
Iku odo yii n gara gan oo
NYSC! NYSC!! NYSC!!! E fura oooo, oro yi n fe amojuto
Hmmm, e wo ju gbogbo re lo, iku ojiji ko ni kogun siwa ooo
Gbayi wa toni ikoro oju lo ba de jare, a o le se alaima se ni
No comments:
Post a Comment