propeller

Propellerads

Saturday, 3 December 2016

Ojogbon Wole Ti Te Oka Niru Mole, Hmmm, Wahala Nbo

 Ogbontarigi onkowe ni orile ede Nàìjíríà ni, òjògbón Wolé Soyinka ló ti mú ìlérí rè se nípa ìwé ìgbé ìlú ti orílè èdè Améríkà rè.
Òjògbón náà so ní ojó etí, ojó kìn-ín-ní osù kejìla, odún 2016 wí pé oun ti mú ìlérí oun tí oun se lásìkò ìpolongo idibo Améríkà wí pé tí Donald Trump ba wolé ìdìbò, oun yóò fa ìwé ìgbé ìlú Améríkà oun ya. Ní báyìí tí oun sì ti fa ìwé náà ya, oun ti pada si orílè èdè Nàìjíríà ti se ilè baba oun ti oun si ti ko orílè èdè Améríkà sílè.
Wolé Soyinka so èyí láti fi àìfara mo àti ai ni àtìleyìn fún Trump rè han. Sùgbón pèlú bi Baba yìí se n je oluko àgbà ni àwon ilé èkó nla meji no orílè èdè Améríkà ní sd ni baba naa kò fi tiyen se rara.

Òjògbón Wolé Soyinka wa so wí pé ìfé inú oun ni oun ti se, ohun to bá wu eni kéni ni kó se àti wí pé oun o ko dí eni kéni lórí lè èdè Nàìjíríà to bá wu láti gba ìwé igbelu náà nítorí iwe náà wulo pupo sùgbón ní toun Wolé Soyinka, oun ti fi Améríkà gegbaa.


Sùgbón sé e o ro wí pé wahala nlá ló n rúgbo bò wá bá Baba àgbà yii, aipe yii ni agbejoro kan kilo fún òjògbón Soyinka wí pé ko ma se dan wo lasa láti fa ìwé igbelu náà ya nítorí Améríkà kò fi nnkan ini rè sere. Nípa ìdí èyí e jé ká máa reti ohun tí Donald Trump yóò se fun baba o.

Ti kannaakannaa ba ti naa eyega {ija nbo, koi ti de}
Gbayiiinaa ni

No comments:

Post a Comment