propeller

Propellerads

Friday, 2 December 2016

Ìwúre Os̩ù tuntun fun gbogbo omo Yoruba. eemeji lo ma wu yin lati kaa. ise iwadi to peye ni

Nje iba fun olodumare, Oba to ni kokoro ile aye lowo
Ope nla ni fun Oba to wa ni ibi giga to n se akoso gbogbo aye
Opo eniyan lo wu ko di ojo oni, iro ni won pa Oba mi oke ko gba bee
Bee ko wu awon kan ki won di ojo oni, gbogbo ogbon ni won da lati gba emi arawon
Allahu rabi ko je ki won raaye koja si sanmo
O wu awa lati di ojo oni Kabi o o si Oba agba si da emi ati iwo si
Ope ooooo
Osu Seere (January) lo, ko se wa seresere

Osu Erele (February) koja, gbogbo ere taa se ko le wa si orun

Osu Erena (March) naa di ohun igbagbe, awa ko deni igbagbe ni tiwa

Osu Igbe (April) gbe eru re danu, igbe iku oro ko jade lenu ebi wa wi pe a ti di agbe gbin

Osu Ebibi (May) bi danu, sugbon aye ko bi wa danu ni tiwa, Olorun o ma se

Osu Okudu (June) naa ko awon eniyan lo, sugbon awa ko di eni ti oku re dun awo eniyan

Osu Agemo (July) pa ile mo o lo, awa ko ba alagemo ati epe re lo

Osu Ogun (August) se titi, opo eniyan ni won fi bo ogun, sugbon awa o ku iku ogun

Osu Owewe (September) we awon eniyan danu, gboingboin lawa wa

Osu Owara (October) se wara wara o gberu re nile, Oba oke ko ma je ki a fi wara wara fi aye sile

Osu Beelu (November) belu igbo pelu awon kan sugbon eyee wo awa re. Opo ojo lo ti ro ti ile ti fi mu, a o fi yo won, a fi n dupe fun Olorun ni.

Ope ooooooooooo
Iwe elesin Musulumi, Iwe elesin Kirisiteni, ati ti awon elesin kan abalaye je ko ye wa wi pe ENI BA DUPE ORE ANA, YOO RI OMIRAN GBA.

Osu Ope (December) la wa yi ooo. Olorun a dupe gbogbo eyi to ti se fun wa seyin. Dakun dabo je ki emi wa la 2016 ki a si ri opo odun laye.
OLORUN OOO: Gbogbo ohun ti a n ro je ko papo mo tie ooo.

Eyin wo le ri kini yii ka, ke si se amin oo.
Ohun ti ma fi pari re naa ni GBAYII

No comments:

Post a Comment