Nnkan selè niju ará ilé ni kò gbó ooo. ogbontarigi onkori nì Alaji Sefiu Alao ni ikú yè lórí rè ni ojó Àbáméta ojó kewàá, osù kejila odún 2016 nígbà tí ó n seré lówó ní ilu Sagamu ní ìpínlè Ogun.Gégé bí ìròyìn se jábò rè: Sefiu Alao n korin lówó níbi ìwúyè olóyè Adétólá Dòsùmu gégé bí Bàbálájé ti Makun labe Oba Timothy Oyèsolá Akínsànyà Orungba 2 kí ìsèlè burúkú náà tó selè.
Nígbà tí ikò NAIJ.com n bá òkan nínú àwon omoléyìn Sefiu Alao sòrò,eni náà se àlàyé wí pé wàhálà náà bé sílè nígbà tí olóyè náà bó sójú agbo tí ó sì n ná owó nla nla repete fun Sefiu Alao tí a tún mò sí omo oko. Ó ní gbàrà tí àwon omo gànfé ríi bí oní nnkan se n nawo fún olórin náà ni wón ya sí ojú agbo wí pé àwon náà fé gba ìpín tiwon naa. Láti ba le àwon ènìyàn yí sá séyin olópàá tí wón gbà gégé bí alábo ló bèrè sí ní yin ìbon ní kosekose títí tí ìbon náà fi ba Sefiu Alao tó korin àti obìnrin kan tó wà ní èbá odo rè lójú agbo nibe.
Nígbà tí Olórun kó Omo oko yo láti jeri oore Olórun látàrí wí pé ibi apá rè òsì ni ìbon náà ti bàá, ó seni láàánú wí pé kádàrá kò se arábìrin tó wà ní ègbé rè lóore nítorí ota ìbon náà pa arábìrin náà lésèkesè ni.

Sùgbón ju gbogbo rè lo, olópàá tó yin ìbon náà tí wón ò dárúko rè naa ti wà ní àtìmólé ní àkàtà àwon olópàá egbé rè tí wón sì ti n fi òrò wá a lénu wò lórí ìsèlè náà.
Nigba ti eni to ye ka saaba di eni to tun fini sinu ewu, se wahala ko wa de bayii
Sefiu Alao Omo oko mo ki e pe Gbayiii fun oyeku re ooo
Nigba ti eni to ye ka saaba di eni to tun fini sinu ewu, se wahala ko wa de bayii
Sefiu Alao Omo oko mo ki e pe Gbayiii fun oyeku re ooo