Fatai Alimi (Birikila)
Haaa, Ise ju ise lo, tibi ju tibi lo o. Kafaya don ile oko meji wo, o si mo eyi to dun ju. Gege bi P.M Express se jabo iroyin;
Kafayat Oyekunle ti jewo ni gbangba wi pe oun ti ba okunrin miran ti won oruko re n je Fatai Alimi to je molemole (bricklayer) lo, ti o si te oun lorun lati lo eyi to ku ni aye oun pelu okunrin naa. Arabinrin naa to je omo odun merindinlogoji (36) ti ko gbogbo eru re kuro ni ile oko re gangan ni osu kewa to lo yii nigba ti oko re rin irin ajo kuro ni ipinle Eko, o si ko lo ba ololufe re tuntun to je birikila yii ti won jo n gbe agbegbe Igbando ni ipinle Eko nibi ti oun ati oko re gangan n gbe.
Sikiratu Oyekunle (Iyawo oloko meji)
O ni oun ti fi ile oko oun ti oruko re n je Suraju Oyekunle to si je oluko ni ile eko ifafiti ipinle Eko (Lagos State University {LASU}) sile nitori oun ati oko ko bi ju omo kan soso lo lati odun metala (13) ti awon ti se igbeyawo, oko oun ko si toju oun pelu. O wa salaye wi pe leyin osu die ti oun pelu ololufe oun titun (birikila) pade ti awon si ni nnkan po bayii ni oun loyun ti oun si n gbe pelu alaafia lodo re. O ni tokan tara ni oun fi fara mo ile kekere ti omokunrin naa ngbe ju ile janran ti oluko LASU naa lo. Kafaya ati omo to bi fun oluko LASU yii ni won si jo n gbe pelu Alimi ololufe re tuntun.
Suraju Oyekunle (Oluko LASU ti won gba iyawo re)
Sugbon owe Yoruba so wi pe iyawo ole la n gba enikan kii gba omo ole. Ni ojo ojobo, ojo kewa, osu kokanla odun 2016 ni awon olopa wa mu arakunrin omo odun merinle logbon naa iyen Alimi birikila, leyin ti Oga tisa ti lo fi ejo re sun ni ago Olopaa. Si iyalenu, Kafaya lo tun lo san owo itusile Alimi ni iye owo egberunlonamarundinlogbon (N25000) ki won le fi Alimi ti o fi odun meji julo sile lati fi han pe kiise nipa ojo ori bi kii se ife otito.
Hmmmm
Alimi ti gba ati iyawo ati omo Oluko LASU ooo.
Ise ju ise lo, Tibi naa si ju arawon lo oo
Abi bee ko?
No comments:
Post a Comment