Friday, 4 November 2016
American Hospital pinnu láti ṣe agbátẹrù fífi ìdí ìwòsàn tó péye múlẹ̀ nínú iṣẹ ìsègùn
American Hospital pinnu láti ṣe agbátẹrù fífi ìdí ìwòsàn tó péye múlẹ̀ nínú iṣẹ ìsègùn
Wọ́n ń ṣe àfihàn àwọn ohun èlò tuntun àti ọ̀nà íi wọ́n ń gbà fi ṣiṣẹ́ ní Medic West Africa 2016
Lati owo Olutayo IRANTIOLA
American Hospital, aṣiwájú lára àwọn ilé ìwòsàn alaádáni àti ọmọ ẹgbẹ́ Mayo Clinic Care Network ti fọwọ́sọ̀yà lórí ìpinnu láti sún iṣẹ́ ìsègùn lọ sí ìpele tó ga jù. Ilé iṣẹ́ yìí yóò ṣe àfihàn àwọn onírúurú ohun èlò tí ó kógo-já nínú iṣẹ́ ìsègùn ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà bíi: Ibi ìtọ́jú ọkàn àti ẹ̀jẹ̀; Ibi ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ àti Ibi tí a ti ń ṣètò gígúnrégé-ojú àti àwọ̀ ara nípasẹ̀ kíkópa nínú Medic West Africa 2016, ibi ètò àfihàn iṣẹ́ ìsègùn tí ó tóbi jùlọ ní Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà tí yóò wáyé ní ọjọ́ kejìlà sí ìkẹrìnlá oṣù kẹẹ̀wá ọdún 2016 ní Eko Convention Centre, Lagos, Nigeria. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí ni yóò fàyè fún ìjíròrò àti ìfarakínra àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ìsègùn àti ìlera.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ọ̀gá àgbà American Hospital sọ, wíwà wọn níbi àpérò náà yóò ṣe àfihàn bí ìlera àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ó nífẹ̀ẹ́ sí ètò ìlèra tí ó ji-n-gíri ṣe múmú láyà wọn tó. Nípasẹ̀ èyìí, wọ́n pinnu láti ṣe àwárí àìní àwọn ọmọ Nàìjíríà àti láti bá àwọn àìní náà pàdé. Nínú ìpàdè yìí, American Hospital yóò ṣe àfihàn: Ibi ìtọ́jú ọkàn àti ẹ̀jẹ̀; Ibi ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ àti Ibi tí a ti ń ṣètò gígúnrégé-ojú àti àwọ̀ ara.
Peter Makowski, aláṣẹ àti olùdarí American Hospital tó wà ní Dubai sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “a wà fún pípèsè ìlera tí ó yè kooro ní ọ̀nà tí ó ga jùlọ pẹ̀lú ìlànà àgbáyé àti pé, dídarapọ̀ wa nínú ìpàdé náà yóò ṣe àfihàn àwọn iṣẹ́ tí a ń ṣe àti ọ̀nà láti jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ nípa wa. A dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Medic West Africa fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti àǹfààní tí wọ́n fún wa láti fìdí ètò ìlera múlẹ̀ ní agbègbe yìí. Àwọn aṣojú u wa ń ṣiṣẹ́ kárakára láti mọ àìní àwọn aláìsàn ní Nàìjíríà àti mọ ọ̀nà láti kojú àwọn ìpèníjà wọ̀nyìí.”
Ètò ọdún yìí yóò ṣe àfihàn àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera bíi ẹgbẹ́rún mẹ́ta-àbọ̀, pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó ń pèse, ṣe àti títa ètò ìlera bíi ọ̀ọ́dúnrún. Ètò náà yóò ṣe àgbékalọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà tí yóò fojúsun kíkọ́ àwọn akópa ní àwọn ohun tí ó wà lójú ọpọ́n nínú ètò ìlera lágbàáyé.
American Hospital gẹ́gẹ́ bí agbátẹrù pàtàkì fún ìpàdé náà yóò wà ní ibi ìdúró akọ́kọ́, HO1 nínú u gbọ̀ngàn ìpàdé.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment