Kìí s̩e ìròyìn
tuntun pé Alàgbà Trump ló wo̩lé ìdìbò sí ipò ààrè̩ tuntun fún orílè̩
èdè Amé̩ríkà lé̩yìn ìdìbò tó wáyé ní o̩jó̩ ke̩jo̩ os̩ù ko̩kànlá
o̩dún 2016. S̩ùgbó̩n ìròyìn ibè̩ ni ìyàlé̩nu àti bí ò̩gbé̩ni Donald Trump s̩e fè̩yin Hillary Clinton lélè̩
lé̩yìn ò̩pò̩lo̩pò̩ àtakò àti ìgbógun tini láti o̩wó̩ àwo̩n e̩gbé̩
alátakò àti àwo̩n o̩mo̩ ìlú Amé̩ríkà àti àwo̩n ènìyàn jàǹkàn
káàkiri àgbáyé.
Oro naa ba Hilary lojiji
Ó bá àwo̩n ènìyàn lójijì bí alàgbà náà s̩e jáwé
olúborí nínú ìdìbò náà. S̩ùgbó̩n àwo̩n kan so̩ wí pé bóyá nítorí
pé Hilary Clinton jé̩ obìnrin, orilè̩ èdè Amé̩rícà kò sì lè gbà kí
Obìnrin je̩ gàba lórí àwo̩n àti wí pé e̩nu lè ma kàá arábìnrin náà
gé̩gé̩ bí ìwa rè̩ sé̩yìn nígbà tí o̩ko̩ rè̩ wà lórí àlééfà gé̩gé̩
bi ààre̩ Amé̩ríkà. Ìdí nìyí tí wó̩n fi gbò̩nà è̩bùrú yo̩ sí
Hilary Clinton wí pé kàkà kí kìnìún s̩e akápò e̩kù, kí káluku s̩e
o̩de̩ tirè̩ ló̩tó̩ò̩tò̩ àti wí pé kàkà kó̩mo̩dé pamí láyò máa
yáa dó̩gbó̩n síi.
Hilary Clinton gba kamu
Ní èrò tiyín, ǹjé̩
òótó̩ ni ò̩rò̩ yìí?
Gbayii fún gbogbo o̩mo̩
Amé̩ríkà
No comments:
Post a Comment