propeller

Propellerads

Saturday, 12 November 2016

BASKET MOUTH TI PARÍ ÈTÒ LÁTI DÍJE FÚN IPÒ ÀÀRE̩ ORÍLÈ̩ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, E̩ WO ÌDÍ RÈ̩



 Bí àwàdà ke̩ríke̩rì lórí, s̩ùgbó̩n níbi eré latí ń mo̩ òótó̩ ò̩rò̩.
Adé̩rìnínpòs̩ónú ò̩gbé̩ni Bright Okpocha tí gbogbo ènìyàn mò̩ sí Basket Mouth ti fi èrò o̩kàn rè̩ hàn láti díje fún ipò Ààrè̩ orílè̩ èdè Nàìjíríà
Ó so̩ eléyìí gé̩gé̩ bí ìlérí rè̩ tó ti s̩e làsìkò ìpolongo ìdìbò Amé̩ríkà wí pé ohun tó bá ti mú Donald Trump wo̩lé ìdìbò gé̩gé̩ bí Ààrè̩ ní Amé̩ríkà, oun náà (Basket Mouth) yóò díje du ipò ààrè̩ orílè̩ èdè Nàìjíríà. Pè̩lú ìfé̩ O̩ló̩run, Trump ló borí ìdíje náà nígbà tí ó fè̩yìn Hilary Clinton lé lè̩.
Ní kété tí wó̩n kéde Trump gé̩gé̩ bi olùborí ìdíje náà ní o̩jó̩ ke̩sàn-án os̩ù ko̩kanlá o̩dún 2016 ni Basket Mouth náà tún bó̩ sí orí ojú ewé ayélujára e̩lé̩ye̩ rè̩ ìye̩n (twitter) láti fi àwòrán rè̩ tó fé̩ lò fún ìdíje ààre̩ sórí ayélujára náà. E̩ wo àwòrán náà ní ìsàlè̩ àti ohun tí àwo̩n ènìyàn ń wí.

Àko̩mò̩nà rè̩ ni “(make Nigeria bright again) Jé̩ kí ìmó̩lè̩ Nàìjíríà ̀tàn lé̩è̩kan síi”. Bóyá nítorí orúko̩ rè̩ ń jé̩ Bright ló s̩e lo àko̩mò̩nà yìí
Gbógbo ayé ló mò̩ pé aláwàdà ke̩ríke̩rì ni Basket Mouth, s̩ùgbó̩n bó s̩e jé̩ aláwàdà tó yìí,
 ǸJÉ̩ TÍ BASKET MOUTH BÁ DÍJE DU IPÒ ÀÀRE̩, ǸJÉ̩ È̩YIN YÓÒ DÌBÒ FUN?

No comments:

Post a Comment