Ibanuje nla gbale gbo ni adugbo Ekwulumili ni Nnewi ni ipinle Anambra nigba ti won sin awon omo iya mefa ti won ku ni ojo kan naa, wakati kan naa. Ohun ti o fa sababi iku won ni ounje ti won jo je ti enikan si ti fi majele si inu re fun won.
Oruko awon omo naa ni: Chukwuebuka (omo odun 17), Chinemere (odun 15), Afomachukwu (odun 13), Onyekachukwu
(omo odun 13), Chekwubeckwu (odun 11), ati Chukwuziterem, (odun 7).
Sugbon gege bi Ewenike Ogechukwu to gbe aworan isinku awon omo naa si ori oju iwe (Facebook) re wi pe wo ko ti le so pato eni ti o fi majele sinu ounje awon omo naa.
O tun fi kun wi pe awon agbofinro ti n se abewo si ibi isele naa, won si ti n se ifimufinle ati iwadii nipa bi majele se de inu ounje awon omo iya mefa naa. Eyi ni oun ti okunrin naa ko:
“Enikan ti won ko mo fi majele sinu ounje ti won toju sile ni adubo Ekwulumili ni ipinle Anambra. Sugbon iwadii ti n lo nipa re. Eni to se eyi ko gbodo lo lai jiya.” (Ede geesi lo fi ko awa la tu si Yoruba)
Enikan naa to je omo adugbo naa ti oruko re nje Chidozie Venantiu naa to so si oju ewe ayelujara re lati fi edu okan re naa haa nipa isele naa wi pe:
“Gbogbo agbegbe yii ti n gbona lati ana, Ebi kan padanu omo iya mefa nipase majele inu ounje".
No comments:
Post a Comment