Sunday, 13 November 2016
OLODE TUN TI PA AKEKOO KAN TO SESE SE TAN OOOO. KILODE GAN
Akekoo kan to sese setan ile eko fafiti ti ipinle Abia (Abia State University (ABSU)) lo pade iku re lati owo olode kan nigba ti ija kan be sile laarin won ni ile awon akekoo to wa ni ita ile iwe ni ojo isegun to koja yii (8/11/2016 ). Iroyin jabo re wi pe arakunrin to ku naa ti oruko re n je Maxwell Okpubo je okan lara awon ogbontarigi ninu egbe okunkun.
Wahala naa be sile ni aago mefa irole, nigba ti Oloogbe Maxwell lo se abewo si orebirin re ti won pe oruko re ni Dammy ni ile ti won pe ni Pentagon Lodge ti o sunmo ile iwe won. Nigba ti o de ibe, o ri awon akekookurin melo kan ni iwaju ita ile naa ti won takuro so. Gege bi alagbara ati bo se mo pe oun lenu to nigba to wa ni ile iwe, o pase pe ki okan ninu awon akekookunrin naa lo ba oun pe orebinrin oun wa ninu ile. Haaa, egbin gbun, eyin egbon asiko yin ti le, e lo sempe. Omokunrin naa daa lohun pe oun o le lo baa pee. Eemi, ni iwo n kose fun, abi o mo eni to n ba e soro ni. Aafi GBOOO!!!. Won ni ni Maxwell gba omokunrin naa leti.
CAMPUSLIFE jabo iroyin wi pe bayii ni Olusogba to n so ile naa ti oruko re n je Philips jade si won to si pase pe ki Maxwell fi ile naa sile. Inu bi Oloogbe Maxwell si iru gbolohun ti olusogba naa so, o si fi eleyoro sile, o n le adiye. O gbagbe eni to n baja tele, o so ija naa di ti baba olode. Oro di paakirakita, Maxwell ati Philips to je olode bere ija laaarin arawon.
Eni ti oro se oju re sugbon to ni won ko gbodo daruko oun se alaye wi pe, nigba ti ija naa n lo ni Maxwell lo wa irin ti enu re mu kan to si saa mo Philips ninu. Inu beje, haaaa, emi lo gbeje lara re. Oo ni lo fun eyi too se yii, ka to wi ka to fo, Philips naa wo iyara re, o fa obe yo, aafi SHA! SHA!! SHAA!!!. Philips si gun Maxwell titi to fi gun un pa.
Ni bayii, Philips wa ni ile iwosan kan to ti n gba itoju ara re. Nigba ti won bii, o ni ohun pa Maxwell nitori aabo ara oun ni, nitori eni ba yara logun gbe. A ri gbo pe oloogbe Maxwell se ayeye ojo ibi odun marundinlogbon (25) re ni Osu kewa to lo yii ni.
O ma se ooo.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment