propeller

Propellerads

Wednesday, 2 November 2016

Ìwúre Os̩ù tuntun



Mo kí gbogbo wa pé a kú àmójúbà os̩ù titun yìí oo. Lágbára O̩ló̩run
·       Wo̩n ò ní s̩ù wá so̩nù nínú os̩ù yí
·       A ò ní di e̩ni àwá tì nínú os̩ù yìí
·       Aburú ó kéré, ó tóbi kò ní jé̩ tiwa àti àwo̩n e̩bí wa
·       Ire iwájú, ire è̩yìn kó wo̩lé tò̩ wá wá
·       Ikú òjijì kò ní jé̩ tiwa
·       A ò ní jo̩ e̩ni tí wó̩n ń wa, àwa náà kò sì ní wá èèyàn
·       Gbogbo aláboyún tó ye̩ kó bí lós̩ù yìí kò ní bí i sí àjùlé ò̩run
·       Gbogbo àwo̩n tó ti ń wojú O̩ba òkè fún o̩mo̩ yóò ré̩rìn ayò̩ lós̩ù yìí
·       Is̩é kékeré owó ńlá ni tiwa lágbára o̩ba òkè
·       Ilé kò ní lé wa, ò̩nà kò ní nà wá, is̩é̩ kò ní di ìs̩é̩
·       Mo gbà àdúrà, orílè̩ èdè Nàìjíríà yóò dára láìpé̩ lágbára O̩ba tí kò sí irú rè̩
·       Gbogbo àwa táa wà lájò, a óò kó èrè oko délé oo
·       Ní òpin gbogbo rè̩, àwa táa rí os̩ù yí. a óò rí os̩ù tó ń bò̩

S̩ùgbó̩n è̩yin náà e̩ má ro ibi sí e̩lòmíràn, gbogbo e̩ni tó bá ní kí te̩nìkan bàjé̩, àwa ò so̩ pé kí tirè̩ bàjé̩ òó, s̩ùgbó̩n Èdùmàrè má jè̩ kí apá ò̩tá ó ká wa.

E̩ni tó bá mo̩ Yorùbá kà nìkan ló lè s̩e àmí sí àdúrà yìí
Óyá ÀMÍN RE̩ DÀ
Gbayìi ́fún e̩ni tó bá ríi kà.

Ó s̩eni láànú pé a ò ko̩ è̩dà àlè̩móde yìí sí èdè Gè̩é̩sì. À mò̩ó̩mò̩ ni, a fi bu o̩lá fún èdè Yorùbá ni àti gbogbo o̩mo̩ Yorùbá ni.

No comments:

Post a Comment