Arewa osere fiimu omo ile Gana ni, Michel Majid so wi pe oun ti di atunbi, oun si n se ileri wi pe lati akoko yi lo enikeni ko ni ri ihoho ohun mo ninu fiimu ati wi pe ohun o si ni kopa nibi fiimu to maa ni se pelu sise afihan ihoho eni.
Fun bi ai moye odun seyin ni ogbontarigi osere naa ko fi gbagbo ninu esin kankan ti ko si ni gbagbo wi pe Olorun wa, sugbon ni ale ojo kan, nigba ti o wa ni iwaju ile re, o gboju soke wo oju orun. Bayii ni imisi olorun si sokale si okan re to si yii lokan pada to fi gba wi pe Olorun wa to si n da ara re lebi wi pe kilode ti oun ko fi ti gba tipe.
Osere naa, to ti ni igbagbo tuntun, ti iroyin tile gbee wi pe o ti di alamojuto ile ijosin kan, to si n so fun awon ololufe re wi pe ki won reti iwa obun kan lati owo ohun mo.
Nigba ti o n ba ile ise redio HitzFm soro, Majid so wi pe nibayi oun setan lati fa okan awon ololufe oun si ibi iwa daadaa pelu iwa daadaa ni.
Oro re lo bayii wi pe:
"E o ni ri ihoho mi, e o ni ri mi ki n kopa ninu iran ti yoo fa aleebu si ihoho eda, e o ni gbo oro alufansa lenu mi mo ninu fiimu sugbon e oo ma ri eko nla ti yoo ma fa okan yin lo si ibi sise daadaa to ga ju. Ni ti paapaa, n oo din ilana igberekale mi ku yato si ti janduku ati ipanle ti e ti mo tele. N oo se iwontun wonsi si gbogbo awon iran ti o le fa ifaseyin ba iwa omoluabi eniyan, yala nipa ihoho ni tabi iwa buruku. Mo le je eniyan buruku ninu fiimu oo, sugbon odiwon yoo wa fun iru eniyan buruku bee ti yoo yato si bi mo ti n se e tele. (awa la tu si ede Yoruba)
(rivroom.com)
A ki Majid ku oriire, sugbon se ka ba gbogbo awon fiimu ti a ti ri ihoho re je ni abi ka pa awon ihoho re ti a ri re kuro lokan wa. Erin pami
Amo o, Sugbon oo, Tabi ooo, Ati pe oo, Hmmm
Tuesday, 15 November 2016
Oga oo, Ile ejo da ewon odun meji fun arakunrin nitori o gbe iresi kongo mewa
Ile ejo kekere kan to wa ni ilu Osogbo ni ojo Aje lo da ewon odun meji fun okunrin omo odun mokandinlogbon kan ti oruko re n je Fatai Ganiyr nitori o gbe kongo iresi 10 ati igo oti merin.
Igbejo ti koko waye ni ojo kewa, osu kewaa odun 2016 nigba ti agbejoro fun olupejo ti oruko re n je Mereti Wilson se alaye wi pe kongo iresi mewaa naa je egberun mejo (N8000) ti igo oti merin naa si je egberun mewaa (N10,000). O se alaye wi pe Fatai ja ilekun iso arabinrin Okeola Comfort to wa ni agbegbe Oke-Ayepe ni Gbogan ni aago meji oru, o si ji awon oja naa ti obinrin naa n ta.
Mereti so bayii wi pe:
“Fatai ti se lodi si ofin to si ni ijiya ninu labe ofin abala 283 ati 414 ti iwa odaran, Ori 34, ese II, ofin ipinle Osun, orile ede Naijiria 2002, ijiya re si wa ni abe ofin ni abala 390(9) ti iwa odaran, Ori 34, ese l.II, ofin ipinle Osun orile ede Naijiria, 2002.”
Sugbon ni tire, agbejoro fun odaran iyen ogbeni Seye Oluyombo bebe fun idariji ati fifi oju aanu woni fun onibarare nipa pe won gba pe o jebi esun mejeeji ti won fi kan an.
Adajo ile ejo naa, Iyaafin Adejumoke Olowolagba, o foju han pe Ganiyu jebi esun mejeeji ti won fi kan nipa pe ogbinyanju lati jale, o si ri ole naa ja. Nipa idi eyi, ile ejo da ewon odun meji fun un.
Ibeere mi ni wi pe nigba ti eni to ji N18,000 ba lo si ewon odun meji ti a o si so fun wi pe ko ko ohun to ji sile, kini idajo to ye fun eni to ji N500,000,000,000.
Orile ede Naijiria mo gbosuba fun eto idajo wa ooooo hmmmmmm.
Monday, 14 November 2016
Oluko LASU ti won soole. Birikila lasan lasan lo gbe gori esin abomu. Eyin lekisora eyaa maa sora ooo. Iwe ko ni won fi n se oo
Fatai Alimi (Birikila)
Haaa, Ise ju ise lo, tibi ju tibi lo o. Kafaya don ile oko meji wo, o si mo eyi to dun ju. Gege bi P.M Express se jabo iroyin;
Kafayat Oyekunle ti jewo ni gbangba wi pe oun ti ba okunrin miran ti won oruko re n je Fatai Alimi to je molemole (bricklayer) lo, ti o si te oun lorun lati lo eyi to ku ni aye oun pelu okunrin naa. Arabinrin naa to je omo odun merindinlogoji (36) ti ko gbogbo eru re kuro ni ile oko re gangan ni osu kewa to lo yii nigba ti oko re rin irin ajo kuro ni ipinle Eko, o si ko lo ba ololufe re tuntun to je birikila yii ti won jo n gbe agbegbe Igbando ni ipinle Eko nibi ti oun ati oko re gangan n gbe.
Sikiratu Oyekunle (Iyawo oloko meji)
O ni oun ti fi ile oko oun ti oruko re n je Suraju Oyekunle to si je oluko ni ile eko ifafiti ipinle Eko (Lagos State University {LASU}) sile nitori oun ati oko ko bi ju omo kan soso lo lati odun metala (13) ti awon ti se igbeyawo, oko oun ko si toju oun pelu. O wa salaye wi pe leyin osu die ti oun pelu ololufe oun titun (birikila) pade ti awon si ni nnkan po bayii ni oun loyun ti oun si n gbe pelu alaafia lodo re. O ni tokan tara ni oun fi fara mo ile kekere ti omokunrin naa ngbe ju ile janran ti oluko LASU naa lo. Kafaya ati omo to bi fun oluko LASU yii ni won si jo n gbe pelu Alimi ololufe re tuntun.
Suraju Oyekunle (Oluko LASU ti won gba iyawo re)
Sugbon owe Yoruba so wi pe iyawo ole la n gba enikan kii gba omo ole. Ni ojo ojobo, ojo kewa, osu kokanla odun 2016 ni awon olopa wa mu arakunrin omo odun merinle logbon naa iyen Alimi birikila, leyin ti Oga tisa ti lo fi ejo re sun ni ago Olopaa. Si iyalenu, Kafaya lo tun lo san owo itusile Alimi ni iye owo egberunlonamarundinlogbon (N25000) ki won le fi Alimi ti o fi odun meji julo sile lati fi han pe kiise nipa ojo ori bi kii se ife otito.
Hmmmm
Alimi ti gba ati iyawo ati omo Oluko LASU ooo.
Ise ju ise lo, Tibi naa si ju arawon lo oo
Abi bee ko?Sunday, 13 November 2016
IKUNLE ABIYAMO OOO. OMO IYA MEFA KU NI OJO KAN NAA. EWO IRU IKU TO PA WON. IRU EYI KO NI JE IPIN WA O
Ibanuje nla gbale gbo ni adugbo Ekwulumili ni Nnewi ni ipinle Anambra nigba ti won sin awon omo iya mefa ti won ku ni ojo kan naa, wakati kan naa. Ohun ti o fa sababi iku won ni ounje ti won jo je ti enikan si ti fi majele si inu re fun won.
Oruko awon omo naa ni: Chukwuebuka (omo odun 17), Chinemere (odun 15), Afomachukwu (odun 13), Onyekachukwu
(omo odun 13), Chekwubeckwu (odun 11), ati Chukwuziterem, (odun 7).
Sugbon gege bi Ewenike Ogechukwu to gbe aworan isinku awon omo naa si ori oju iwe (Facebook) re wi pe wo ko ti le so pato eni ti o fi majele sinu ounje awon omo naa.
O tun fi kun wi pe awon agbofinro ti n se abewo si ibi isele naa, won si ti n se ifimufinle ati iwadii nipa bi majele se de inu ounje awon omo iya mefa naa. Eyi ni oun ti okunrin naa ko:
“Enikan ti won ko mo fi majele sinu ounje ti won toju sile ni adubo Ekwulumili ni ipinle Anambra. Sugbon iwadii ti n lo nipa re. Eni to se eyi ko gbodo lo lai jiya.” (Ede geesi lo fi ko awa la tu si Yoruba)
Enikan naa to je omo adugbo naa ti oruko re nje Chidozie Venantiu naa to so si oju ewe ayelujara re lati fi edu okan re naa haa nipa isele naa wi pe:
“Gbogbo agbegbe yii ti n gbona lati ana, Ebi kan padanu omo iya mefa nipase majele inu ounje".
OLODE TUN TI PA AKEKOO KAN TO SESE SE TAN OOOO. KILODE GAN
Akekoo kan to sese setan ile eko fafiti ti ipinle Abia (Abia State University (ABSU)) lo pade iku re lati owo olode kan nigba ti ija kan be sile laarin won ni ile awon akekoo to wa ni ita ile iwe ni ojo isegun to koja yii (8/11/2016 ). Iroyin jabo re wi pe arakunrin to ku naa ti oruko re n je Maxwell Okpubo je okan lara awon ogbontarigi ninu egbe okunkun.
Wahala naa be sile ni aago mefa irole, nigba ti Oloogbe Maxwell lo se abewo si orebirin re ti won pe oruko re ni Dammy ni ile ti won pe ni Pentagon Lodge ti o sunmo ile iwe won. Nigba ti o de ibe, o ri awon akekookurin melo kan ni iwaju ita ile naa ti won takuro so. Gege bi alagbara ati bo se mo pe oun lenu to nigba to wa ni ile iwe, o pase pe ki okan ninu awon akekookunrin naa lo ba oun pe orebinrin oun wa ninu ile. Haaa, egbin gbun, eyin egbon asiko yin ti le, e lo sempe. Omokunrin naa daa lohun pe oun o le lo baa pee. Eemi, ni iwo n kose fun, abi o mo eni to n ba e soro ni. Aafi GBOOO!!!. Won ni ni Maxwell gba omokunrin naa leti.
CAMPUSLIFE jabo iroyin wi pe bayii ni Olusogba to n so ile naa ti oruko re n je Philips jade si won to si pase pe ki Maxwell fi ile naa sile. Inu bi Oloogbe Maxwell si iru gbolohun ti olusogba naa so, o si fi eleyoro sile, o n le adiye. O gbagbe eni to n baja tele, o so ija naa di ti baba olode. Oro di paakirakita, Maxwell ati Philips to je olode bere ija laaarin arawon.
Eni ti oro se oju re sugbon to ni won ko gbodo daruko oun se alaye wi pe, nigba ti ija naa n lo ni Maxwell lo wa irin ti enu re mu kan to si saa mo Philips ninu. Inu beje, haaaa, emi lo gbeje lara re. Oo ni lo fun eyi too se yii, ka to wi ka to fo, Philips naa wo iyara re, o fa obe yo, aafi SHA! SHA!! SHAA!!!. Philips si gun Maxwell titi to fi gun un pa.
Ni bayii, Philips wa ni ile iwosan kan to ti n gba itoju ara re. Nigba ti won bii, o ni ohun pa Maxwell nitori aabo ara oun ni, nitori eni ba yara logun gbe. A ri gbo pe oloogbe Maxwell se ayeye ojo ibi odun marundinlogbon (25) re ni Osu kewa to lo yii ni.
O ma se ooo.
Saturday, 12 November 2016
BASKET MOUTH TI PARÍ ÈTÒ LÁTI DÍJE FÚN IPÒ ÀÀRE̩ ORÍLÈ̩ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, E̩ WO ÌDÍ RÈ̩
Bí àwàdà
ke̩ríke̩rì lórí, s̩ùgbó̩n níbi eré latí ń mo̩ òótó̩ ò̩rò̩.
Adé̩rìnínpòs̩ónú
ò̩gbé̩ni Bright Okpocha tí gbogbo ènìyàn mò̩ sí Basket Mouth ti fi èrò
o̩kàn rè̩ hàn láti díje fún ipò Ààrè̩ orílè̩ èdè Nàìjíríà
Ó so̩
eléyìí gé̩gé̩ bí ìlérí rè̩ tó ti s̩e làsìkò ìpolongo ìdìbò
Amé̩ríkà wí pé ohun tó bá ti mú Donald Trump wo̩lé ìdìbò gé̩gé̩
bí Ààrè̩ ní Amé̩ríkà, oun náà (Basket Mouth) yóò díje du ipò ààrè̩
orílè̩ èdè Nàìjíríà. Pè̩lú ìfé̩ O̩ló̩run, Trump ló borí ìdíje
náà nígbà tí ó fè̩yìn Hilary Clinton lé lè̩.
Ní kété
tí wó̩n kéde Trump gé̩gé̩ bi olùborí ìdíje náà ní o̩jó̩ ke̩sàn-án
os̩ù ko̩kanlá o̩dún 2016 ni Basket Mouth náà tún bó̩ sí orí
ojú ewé ayélujára e̩lé̩ye̩ rè̩ ìye̩n (twitter) láti fi àwòrán rè̩
tó fé̩ lò fún ìdíje ààre̩ sórí ayélujára náà. E̩ wo àwòrán náà
ní ìsàlè̩ àti ohun tí àwo̩n ènìyàn ń wí.
Àko̩mò̩nà
rè̩ ni “(make Nigeria bright again) Jé̩ kí ìmó̩lè̩ Nàìjíríà ̀tàn
lé̩è̩kan síi”. Bóyá nítorí orúko̩ rè̩ ń jé̩ Bright ló s̩e lo àko̩mò̩nà
yìí
Gbógbo
ayé ló mò̩ pé aláwàdà ke̩ríke̩rì ni Basket Mouth, s̩ùgbó̩n
bó s̩e jé̩ aláwàdà tó yìí,
Subscribe to:
Posts (Atom)