propeller

Propellerads

Monday, 31 October 2016

Orí Adé ti wàjà oooo. Oba wo ló wàjà


Ikú pabírí, abírí kú
Ikú pa abìrì, abìrì ròrun àrè mabò
Ikú pa agbe, kò lè dáró
Ikú pa àlùkò, osù kò sí ní ìkáwó rè mó
Ikú pa lékènlèké, lékènlèké kò réfun kùn mo
Ikú pa ONÍLÈPA ti ILU ÌLÈPA, Oba Abdul Fatai Oládipúpò ni ànà ogbòn ojó, osù kewàá odún 2016. 30 / 10 / 2016.
Ìlèpa wa ni ìkojá ìlú Ifò ní ìjoba ìbílè Ifo ní ìpínlè Ògùn.
Oba Abdul Fatai Oládipúpò ti wàjà, ìlèpa kò ni tu oo. Àse.
Omo Ìlèpa e kú orò èèyàn
Omo Ifò, e kú ìrójú
Omo Yorùbá, e kú ara féra kù Oba tó wàjà.

Gbogbo wa la ó gbèyìn àwon àgbà wa oo
Gbayii fún Oba tó wàjà. 

Fún èdè gèésì, e te ààyè

Friday, 28 October 2016

Tí e̩ bá rí àwo̩n àwòrán yìí, ohun tó lè s̩e̩lè̩ síiyín nìwò̩n yí: DÚPÉ̩ FÚN O̩LÓ̩RUN, RÉ̩RÌN-ÍN, KÁ ÀÁNÚ, E̩ Ó SÌ KÓ̩ È̩KÓ̩, E̩ Ó SÌ FÉ̩RÀ̀N LÁTI PÍN KIRI



Àwo̩n àgbà ló bò̩ wó̩n so wí pé, nínú gbogbo àìda, dáadáa kan yóò s̩ì wà níbè̩. Àwo̩n àwòrán ìsàlè̩ yìí lè pani lé̩rìn-ín s̩ùgbó̩n wo̩n kò s̩àì ní è̩kó̩ kan tàbí òmíràn tí wo̩n yóò kó̩ wa. E̩ jé̩ ká jo̩ yè̩é̩ wò

1. Ìdájó̩ tó dárajù fún ìfípá báni lò pò̩
Gé̩gé̩ b́í e̩ s̩e ríi lókè, tí wó̩n bá ń s̩e irú ìdájó̩ yìí fún àwo̩n okùnrin tó bá fi tipá bá obìnrin lò, ó dámi lójú wí pé è̩rù yóò bà wó̩n láti wu ìwà pálapála náà.

2. Hmmm, Ebi tí ń pani kú
 Bé̩è̩ni, o̩mú ìyá yìí kéré, o̩mo̩ náà sì lè gbe̩ bíi ìgbálè̩ agbé póò, s̩ùgbó̩n ówu àwo̩n náà láti wà ní àlááfíà bí tìe̩ s̩ùgbó̩n ebi kò dáa lára. S̩óo wá ríi wí pé àánú ni ìwó̩ rí gbà. Tó bá jé̩ wí pé èmi ni ìwo̩ ni o̩pé̩ ni màá dá. Dúpé̩ tìe̩ jò̩ó̩.

3. Haaa, Kí lódé tí e̩ joyè adérùpo̩kò̩?
 E wo àwo̩n o̩kò̩ méjì tó wà lókè yìí, pè̩lú wí pé è̩yà ara wo̩n ti relé ogbó tó, wó̩n s̩ì fi ń kó e̩rù, kìí wá s̩e e̩rù kékeré, e̩rù tó tún ju tiè̩ lo̩ ni. Ìye̩n ni pé è̩yà ara kó̩ la fé̩ lò bí kìí s̩e é̩ńjínì tó wà nínú rè̩. O̩kàn re̩ ni é̩ńjìnì tì́re̩. S̩ùgbó̩n e̩ wo èyí tó wà ní ìsàlè̩ yìí, è̩yà ara tirè̩ dára, s̩ùgbó̩n irú e̩rù tí àwo̩n tòkè yìí ńkó lòhun náà ń kó. Tí ó bá tè̩ síwájú pè̩lú e̩rù yìí òun náà kò ní pé̩ relé ogbó bíi tàwo̩n tòkè yí. È̩kó̩ inú rè̩ ni wí pé, má s̩e s̩e ko̩já ìkápá re̩, bí bé̩è̩ kó̩, ìyo̩nu ni ìgbè̩yìn rè̩.



4. Ìdáàbòbò nítorí àlùbó̩sà
È̩rín kèékèé. Ohun tó mú arábìnrin yì̩í tó lè fi akoto o̩ló̩kadà dáàbò bo ara rè nítorí kí àlùbó̩sà má baà kó síi lójú kó baà má ké. Kílódé tí ìwo̩ náà kò fi lè lo ò̩nà ko̩nà láti dáàbò bo ara rè̩ ló̩wó̩ ohun tó lè fa igbe fún e̩.

5. Àkísà ti lògbà rí kótó di as̩o̩ e̩lé̩gbin
Ìyàwó dùn ló̩s̩ìngín. S̩ùgbó̩n bó s̩e wá dùn tó náà, ló̩jó̩ kan, e̩wà ara wa máa s̩á. O̩jó̩ kan la jé̩ olólùfé̩ tuntun, o̩jó̩ kan náà ni a óò di arúgbó tuntun. E̩ gbìnyàn jú kí alé̩ lè san wá ju òwúro̩ lo.

6. O̩mo̩ tó bá máa jás̩àmú, kékeré ló ti máa je̩nu s̩ámú s̩ámú
Mo ré̩rìn-in músé̩. Àwo̩n o̩mo̩ yìí ń s̩e àpe̩e̩re̩ bí wó̩n ti ń wa ò̩kadà ló̩nà àrà. E̩ káre, o̩mo̩ tó bá máa jás̩àmú kékeré ló ti máa je̩nu s̩ámú s̩ámú, ló̩jó̩ kan èrò yín yóò wá sí ìmús̩e̩. Ìwò̩ náà gbìnyànjú ló̩nà ko̩nà láti jé̩ kí èrò ré̩ di òtító̩.

7. Eyah, Kò sì ò̩nà míràn láti gbé e gbà àfi kí wó̩n lo èyí tí wó̩n rí
Àwo̩n kan ní oúnje̩ wo̩n ò lè je̩é̩. Àwo̩n kan lè je̩ s̩ùgbó̩n wo̩ kò  rí jíjé̩ mímu. Tí ìwo̩ bá ríjé̩ tóò sì rí mu, èyí tó dára jù fún e̩ ni láti dúpé̩ fún O̩ló̩run O̩ba tó pèsè rè̩ fún e̩. Nípa ìdí èyí jáye jé̩jé̩ kóo ba lè jáyé pé̩.

Mo rò wí pé a óò ti rí è̩kó̩ kan kó̩ gé̩gé̩ bí mo s̩e so̩ sókè, èyí tí yóò dára ju ni kóo pín ò̩rò̩ yí fún àwo̩n tó kù láti kó̩ è̩kó̩ bíi tìre̩, kí e̩ dè̩ máa gbàgbé láti máa ye̩ búló̩ò̩gì yí wò fún ìròyìn gbanko̩gbì

E̩ tún lè ka ìròyìn yí ní èdè gè̩é̩sì lóri: http://babayorubaonthebroadcast.blogspot.com.ng

Wednesday, 26 October 2016

E̩ wo ohun tí ìfe̩sè̩wo̩nsè̩ Chelsea àti Man U dá sílè̩ nínú e̩bí yìí. È̩yin o̩kùnrin e̩ s̩e jé̩jé̩ kè̩, è̩yin obìnrin è̩yin náà e̩ ye ro ìròkurò




O̩jó̩ burúkú ès̩ù gbomi mu ni o̩jó̩ Àìkú, o̩jó̩ ke̩tàlélógún, os̩ù ke̩wàá, 2016 jé̩ fún àwo̩n olólùfé̩ e̩gbé̩ agbá bó̩ò̩lù Manchester United nígbà tí e̩gbé̩ agbá bó̩ò̩lù Chelsea lùwó̩n ní pàs̩án 4 – 0. Ohun tó wà pani lé̩rìn-ín níbè̩ ni pé ò̩pò̩lo̩pò̩ nínú àwo̩n oló̩lùfé̩ Man U ni wó̩n fi ìkanra ò̩rò̩ náà mó̩ àwo̩n ará ilé wo̩n. È̩yin náà e̩ ye̩ ohun tí Muritala Habeeb Herdemola so̩ sí ojúìwé (facebook) rè̩ fún àpe̩e̩re̩ irú ìkanra àwo̩n o̩mo̩ Man U: (Muritala ko̩ó̩ ní èdè gè̩é̩sì àwa la tú u sí èdè Yorùbá)

* O̩KO̩ ÀTI ÌYÀWÓ, WÓ̩N DÁKÉ̩ RÓ̩RÓ̩ NÍ ORÍ ÌBÙSÙN*
Ìyàwó ń ronú:
Kílódé tí kò bámi sò̩rò̩?
S̩é ó ń ronú obìnrin míràn ni?
Àbí ó ti ń rí e̩lòmíràn ni?
S̩é mi ò re̩wà lójú rè̩ mó̩ ni?
S̩é mo ti wá di è̩gbin lójú rè̩ ni?
S̩é ó ti ń kórìírà àwo̩n ìs̩aralógé mi ni?
Kílódé tí kò fi bámi sò̩rò̩ láti ìgbà tó ti dé?
Mo mò̩ pé ìyá rè̩ kò fé̩ràn mi, bóyá wó̩n sì ti ń pèsè ìyàwó míràn fún un ni?
S̩é bí mo s̩e máa wá di ìyá ń dágbé rèé…?
Olúwa, jò̩wó̩ bámi dáàbò bo ìgbéyàwó mi.
KÍNI Ó Ń BÍ I NÍNÚ?
Lé̩è̩kan náà ni ó fi ìgboyà bèèrè ò̩rò̩ ló̩wó̩ o̩ko̩ rè̩, “Olólùfé̩ mi, Kílodé tí ó fi bámi sò̩rò̩? Kíni mo s̩e fún e̩ tí mo fi tó̩ sí irú ìwà yìí?” omi sì ń jábó̩ lójú rè̩.
O̩ko̩ rè̩ yíjù padà sì i, ojú rè̩ pó̩n, ìbínú súyo̩ lójú rè̩, ó sì fi ìbínù dá ìyàwó rè̩ lóhùn wí pé *”Báwo ni Chelsea lásán làsàn s̩e máa na Man U ní 4 – 0 tí a sì ní agbá bó̩ò̩lù bíi Rashford, Pogba àti Ibramovic lórí pápá?”*

Tó bá jé̩ è̩yin ni arábìnrin náà kí le̩ máa s̩e

Tó bé̩è̩ ju bé̩è̩ lo̩, orílonís̩e lò̩rò̩ bó̩ò̩lù àfe̩sè̩gbá, Man U e̩ gbìnyànjú ju bé̩è̩ lo̩ ní ìgbà míràn

Gbayii fun gbogbo olólùfé̩ bó̩ò̩lù afesegba

E̩ te̩ ààyé yí láti ka ò̩rò̩ yí ní èdè gè̩é̩sì: http://babayorubaonthebroadcast.blogspot.com.ng/2016/10/see-what-chelsea-and-man-u-cause-to.html

Ohun tí Obama n se ní ilé oúnje pèlú òkèlè yóò yà yín lénu. Tí Obama bá lè se èyí pèlú oúnje wa, a jé wí pé Nàìjíríà ti n gòkè àgbà.



Nínú gbogbo ònà ni omo orílè èdè Nàìjíríà ti máa n yo lótun pèlú ogbón àtinúdá. Opolo pòfún won gan ni. Sùgbón kìí se wí pé wón ní ogbón àtinúdá nìkan, wón tun máa n ni ilàna ìpolówó àti ìfa okàn eni sí ohun kóhun tí wón bá n se ní gbogbo ìgbà.
Tí a bá n sòrò nípa ìpolówó àti ìfa okàn eni, àwon oní gègé àrà orílè èdè Nàìjíríà máa n lo ohun kóhun tàbí eni kéni láti mú u yin tún se àgbéyèwò ìpolówó náà léèkan síi ohun tí wón se ní ibi náà. Àpeere irú èyí ni àwòrán àràmàndà kan tí wón se sí ilé oúnje tó wà ní ìpínlè Èkó.

Nínú ònà láti lè jé kí ojà wón tún gòkè síi, wón ya olórí orílè èdè Améríka, ìyen Ààre Barrack Obama gégé bí òkan lára àwon tí ó n jeun nínú ilé oúnje náà nínú àlèsóde won. Wón ya ààre náà níbi tí ó ti n je òkèlè. Níwòn ìgbà tó jé wí pé àwon oúnje bíi Èbà, Àmàlà, Ìresì àti Èwà, Obè aláta súésúé àti Iyán ni wón n tà ní ilé oúnje náà, ó sòro láti mo irú oúnje tí ààre Obama n je nínú àwòrán náà. Sùgbón ohun tó dájú ni wí pé òkèlè ni ó n je.
Ààre Obama n jeun ni búkà ilé oúnje ní ìpínlè Èkó. (Àlá tó nira láti se)
Àwon omo orílè èdè Nàìjíríà yóò sáà lo ònà kan láti polówó ojà wón tí yóò sáà joni lójú láti ra ojà náà sá ni. Ejó wa sì kó, áwon àgbà ló n pa òwe wí pé: ìpolówó làgúnmu òwò.

Sé àwòrán yìí kò pani lérìn bí?


Mo féràn orílè èdè yí, mi ò ní paró


GBAYII nlá fún gbogbo oní gègé àrà.

E tún lè ri kà ní èdè gèésì, e lo sí: http://babayorubaonthebroadcast.blogspot.com.ng/2016/10/you-wont-believe-what-obama-is-doing-in.html?m=1 

Tuesday, 25 October 2016

Ìyanu márùndínlógún (15) nípa Al Kurani Alápò̩ó̩nlé. Ó dámi lójú e̩ óò rí è̩kó̩ ko̩, àgààgà nípa Suratu Fatia



1. Ǹjé̩ o mò̩ pé 6236 ni iye e̩se̩ tó wà nínú Kùránì mímó̩?2. Wó̩n dárúko̩ Kùránì nínú Kùránì fúnra rè̩ fún ìgbà 70

3. Nínú orí wo ni wó̩n ti s̩e àlàyé bí wó̩n s̩e dá o̩mo̩ ènìyàn nínú Kùránì? Kó sí iyè méjì nínú Sura Hijr e̩se̩ 26 ni

4. Mo mò̩ pé ò̩pò̩ ènìyàn máa rò wí pé Suratu Ikhlas ni, s̩ùgbó̩n rárá o, Suratul Kausar ni sura tó kéré jùló̩ nínú ìwé mímó̩

5. Bí Suratu Kausar s̩e wá kéré tó, ò̩rò̩ 42 ló wà nínú rè̩

6. Ò̩pò̩lo̩pò̩ lè má mò̩ wí pé Alif  bé̩è̩ni Alif ا ni áràfí tí wó̩n lò jù nínú Kùránì alápò̩nlé

7. Ǹjé̩ e̩ lè gbàgbó̩ wí pé Zaa ni áràfí tí wó̩n lò kéré jù nínú ìwé mímó̩?

8. Sura kan wà nínú Kùránì tó jé̩ wí pé nínú gbogbo e̩se̩ rè̩ ni wó̩n ti dárúko̩ O̩ló̩run, sura náà ni Suratul Mujadala

9. Sura wo ni wó̩n fi ‘Dal’ gbè̩yìn gbogbo e̩se̩ rè̩? Fún àwo̩n tí kò mò̩, Suratul Iklas ni

10. Òmíràn tún rèé, surah wo ni arafi ‘Ra’ gbè̩yìn gbogbo e̩se̩ rè̩? E̩ má ròó jìnà Suratul Kausar ni

11. Ó ye̩ ké̩e̩ ti gbó̩ pé Suratu Yaseen ni o̩kàn Al Kùránì

12. Suratul Fatia ni wó̩n sì pè ní Ìyá Al Kùránì

13. Ò̩pò̩lo̩pò̩ ènìyàn lè má mò̩ pé è̩è̩mejì ni wó̩n so̩ Suratul Fatia kalè̩ (ní Meka àti Medina)

14. Mo rò wí pé e̩ mò̩ pé kìí s̩e suratul Fatia nìkan ló bè̩rè̩ pè̩lú Al-Hamdulillahi. A tún ní àwo̩n surah mé̩rin míràn, àwo̩n náà ni: Suratul Anaam, Kahf, Saba & Fatir

15. Ó yani lé̩nu wí pé nínú gbogbo sura inú Kùránì ni áràfí faf ف ti hàn, àyààfi nínú suratu fatia nìkan. S̩ùgbó̩n níbi tí O̩ló̩run tóbi dé, kàkà kó hàn nínú àwo̩n e̩se̩ inú rè̩, ara orúko̩ sura náà ló ti hàn. Bóyá ohun tí à ń so̩ kòyé, nínú gbogbo àwo̩n sura tó wà nínú Kùránì, gbogbo àwo̩n sura yí ni áràfi náà hàn nínú e̩se̩ wo̩n kan tàbí òmíràn, s̩ùgbó̩n nínú suratu fatia láti òkè délè̩, Faf kò hàn nínú rè̩ rárá. Dípò kó hàn nínú àwo̩n e̩se̩ náà, ara orúko̩ súrà náà ló ti hàn. Allahu ló tóbi ju gbogbo títóbi lo̩.

Ohun kóhun tí mo bá so̩ tó jé̩ òtító̩ tó sì s̩e wá ní àǹfàání, e̩ gbà wí pé pè̩lú àánú àti àtìle̩yìn O̩ló̩run ni, s̩ùgbó̩n èyí tó bá ku díè̩ káàtó, láti o̩wó̩ mi ló ti wá. Allah nìkan ló ní ìmò̩ nípa gbogbo nnkan, kí ó sì s̩e àforij́ì àwo̩n às̩ìs̩e wa.

Olúwa pó̩n wa lé, kí o sì dáàbò bòwá gé̩gé̩ bí o s̩e s̩e fún Al Kùránì Mímó̩.

È̩dà àlè̩móde yìí wà ní ède gè̩é̩sì ni: http://babayorubaonthebroadcast.blogspot.com.ng/2016/10/15-wonderful-fact-about-holy-quran-i.html?m=1

Òsùpá àti Pàsúmà parí ìjà àjùlo tó wà láàárín won. E wo ohun tí Pàsúmà se fún Òsùpá


Òrò yí pa mí léèrín nígbà tí mo rí i. Sùgbón ohun tí mo rò ni wí pé mò n lá àlá ni. E jòwó kí enìkan tètè jí mi lójú orun, kí ilé agódo Fújì tó gbiná oo.


 Òsùpá n kùnlè fún Pàsúmà
Àwòrán yìí n so pe Òsùpá Saheed (Oba orin) n kúlè esè rè fún Àlàbí Pàsúmà (Ògá nlá) tí Pàsúmà náà sì n fàá sókè.
Kíni èrò tiyín nípa àwòrán yìí? Nítorí ní tèmi àwòrán yìí dàbí eni wí pé iná n jó lórí òrùlé ni.
  • Tí èyin bá jé olólùfé Pàsúmà, njé èyín gba àwòrán yìí gbó?
  • Tí èyin bá jé olólùfé Òsùpá, njé èyín gbà pé irú èyí lè selè.
Ju gbogbo rè lo, èyí ni wón pè ní Ìtàgé Fújì

G
Gb
Gba
Gbay
Gbayi
Gbayiiii náà ni mo fé so gégé bí e ti mò.

E má gbàgbé láti ye àlèmóde yìí wò ní ìkànnì wa ní èdè gèésì lórí: http://babayorubaonthebroadcast.blogspot.com.ng/2016/10/osupa-and-pasuma-settle-their-dispute.html?m=1

Monday, 24 October 2016

Ìròyìn ààbò e̩ni ló̩wó̩ ikú fún àwo̩n o̩mo̩ wa E̩ wo bí olólùfé̩ o̩mo̩bìnrin yìí s̩e s̩e ikú paá. Èyí ni wó̩n pè ní ÌFÉ̩ IKÚ



 
Àánú ìkúnlè̩ abiyamo̩ s̩e mí nígbà tí mo rí ìròyìn yí ní ojúìwé ò̩ré̩ mi kan mo sì rò wí pé ó ye̩ kí n mú u wá sí ojú ìwòràn láti kà fún è̩yin olólùfé̩ mi gé̩gé̩ bí ìkéde ìdáàbò bo e̩ni ló̩wó̩ ikú fún àwo̩n o̩mo̩ wa.

Kay Yusuf Sanni ko̩ó̩ síbè̩ wí pé:

Àánú àwo̩n òbí rè̩ ló s̩e mí, kìí s̩e ti o̩mo̩ tó pa ara rè̩
  Lé̩tà tó ko̩ kó tó pa ara rè̩


Gé̩gé̩ bi a s̩e gbó̩, are̩wà o̩mo̩bìnrin yìí, tó jé̩ o̩mo̩ o̩dún méjìdínlógún tó parí ilé è̩kó̩ sé̩kó̩ndírì ní nǹkan bíi ò̩sè̩ mélòó kan sé̩yìn, tí ó sì lè jé̩ wí pé òun ni kì bá je̩ olorí orílè̩ èdè yìí, ló pa ara rè̩ láìpé̩ yìí nítorí ò̩ré̩kùnrin rè̩ fi sílè̩ tó sì bá e̩lòmíràn lo̩ (ò̩ré̩ o̩mo̩bìnrin tó pa ara rè̩) ní o̩jó̩ ke̩rìndínló̩gbò̩n os̩ù keje. (Kay Yusuf Sanni ko̩ó̩ ní èdè gè̩é̩sì, àwa la túu sí èdè Yorùbá)
Kíni e rò nípa o̩mo̩bìnrin yìí?
Ó ga ooo


Nítorí mo ti lòó ti pé̩, e̩ rò wí pé mi ò ní so̩ó̩ mó̩, s̩ùgbó̩n iró̩ ni, mo s̩i máa máa so̩ wí pe GBAYÌÌ fún è̩yin tèmi


Ju gbogbo rè̩ lo̩, e̩ lè ka ìròyìn yìí ní èdè gè̩é̩sì lórí: http://babayorubaonthebroadcast.blogspot.com.ng/2016/10/life-saving-information-see-how-this.html

Bàbá Ìjè̩bú (Kessington Adebukola Adebutu) di o̩mo̩ o̩dún mó̩kànléló̩gó̩rin (81) lónìí 24 / 10 / 2016.



 Bàbá Ìjè̩bú gé̩gé̩ bí gbogbo ènìyàn s̩e mò̩ ó̩ pé o̩mo̩ o̩dún mó̩kànléló̩gó̩rin ní òní o̩jó̩ ke̩rìnlélógún, os̩ù ke̩wàá, o̩dún 2016. Kessington Adébùkó̩lá Adébutú ní alówólódù bí ìyèré tó ni ilées̩é̩ té̩té̩ ńlá tó gbajúgbajà káà kiri orílè̩ èdè Nàìjíríà tí a mò̩ sí Bàbá Ìjè̩bú tí orúko̩ rè̩ gangan ń jé̩ Premier Lotto tí ìjo̩ba fi òǹtè̩ lù ní o̩dún 2001. Adébutú, níbi tí olúwa rò̩ó̩ ló̩rò̩ dé, ní o̩dún 2014, ó ra Ilé Ìtura ìpínlè̩ ògùn (Gateway Hotels) tó wà ní ìlú Abé̩òkúta. A bí alàgbà náà ní o̩jó̩ ke̩wàá, os̩ù ke̩wàá o̩dún 1935 ní Ìpe̩ru Ré̩mo̩ ní ìjo̩ba ìbílè̩ Ìké̩nné̩ ní ìpínlè̩ Ògùn.
Èyí ni àlàyé ráńpé nípa Bàbá Ìjè̩bú:
Orúkò̩ rè̩:    Kessington Adébùkó̩lá Adébutú ((Bàbá Ìjè̩bú)
O̩jó̩ ìbí:       Òwàrà 24, 1935.
Ìlú:              Ìpe̩ru Ré̩mo̩
Ìjo̩ba ìbílè̩:  Ìké̩nné
Ìpínlè̩:         Ògùn
Orílè̩ èdè:    Nàìjíríà
Is̩é̩:              Premier Lotto(Bàbá Ìjè̩bú), Onís̩òwò àti Bùje̩bùdanù
E̩ jé̩ ka jo̩ kí BÀBÁ ÌJÈ̩BÚ wí pé E̩ KÚ AYE̩YE̩ O̩JÓ̩ ÌBÍ

Ó yá e̩ máa kí Bàbá sí inú àlàfó tó wà nísàlè̩ yìí

Fún è̩dà àlè̩móde yìí ní èdè gè̩é̩sì (èdè òyìnbó) e̩ lo̩ sí: http://babayorubaonthebroadcast.blogspot.com.ng/2016/10/baba-ijebu-kessington-adebukola-adebutu.html

Saturday, 22 October 2016

Nje ere wa ninu sise ere tiata nikan sa? E yeewo idi re ti a fi bere


Jije osere fiimu ni orile ede Naijiria, nje o to gege bi ona lati fise se lai fi nnkan miran kun fun eniyan?
Gege bi oro orile ede Naijiria ti ri bayii nipa sise ayederu ise eni, isoro ti o n koju eto oro aje, ati awon ipenija orisiirisii to ku. Ni ero tiyin, nje eyin ro wi pe jije osere ni orile ede Naijiria to lati mu gege bi ona kan soso lati mu owo wole fun eniyan?

Igbagbo opo eniyan ni wi pe ti o ba ti gbajugbaja lati ipase ero amohunmaworan, iyen ja si wi pe lona kan tabi omiran olowo ni e. Nipa idi eyi opolopo eniyan lo n wu lati darapo mo awon osere naa ni gbogbo ona to wu ti ki baa je.

Sugbon Paga!! Ibi ti won fuju si ona ko gbabe ibe rara fun opolopo awon osere naa. Pelu gbogbo iyi ati aponle ti won ri ninu ise naa, won ko yato si awon ara ilu ti ko si owo lowo re kan lo titi (Iyi lari ko si owo). Bee si ni opolopo n ri owo jaburata nidii ise naa.

Ibeere ibe wa ni wi pe
  1. Kini eyin ro wi pe awon ti won rise, lowo nidi ise naa se si i ti won fi rowo mu nidi ise naa?
  2. Ni ero tiyin, kini e lero wi pe awon to ku die kaa to fun nidi ise naa le se ti oro won naa yoo fi ja sayo nibi sise fiimu ni orile ede Naijiri?
E fi esi oro yin si isale alesode yii, kii se si ori ikanni ti e ti ri oro yi ka

Bakan naa e le ri alemode yii ka ni ede geesi (oyinbo) lori: http://babayorubaonthebroadcast.blogspot.com.ng/2016/10/acting-as-nollywood-curse-or-blessing.html

Thursday, 20 October 2016

Aya Aare tun se tuntun oo. Ki tun ni Aisha Buhari tun se?


  Okan yin doti ju idoti funra re lo. Mo mo wi pe e o ti lero wi pe iyawo aare wa tun ti se nnkan ti o ku die kaato sugbon lote yii e ti sii. Eyi ni ohun to sele: Won fun Aisha Buhari ni ami eye ni Brussels lati owo igbakeji olori ilu ati alakoso fun ile okere ati oke okun, mama naa si fi ami eye naa sori awon ologun orile ede Naijiria ti won koju awon alakatakiti gbogbo.
 Aisha Buhari n gba ami eye
Nipa eyin ti e n ro pe ile idana ati awon iyara to ku nikan ni aya are wa wa fun, e ti sii. Ni temi emi a so wi pe  Aisha Buhari wa fun orile ede Naijiria ati ile alawo dudu to ku. Ninu alemode re to fi si ori facebook re lo ti fi ami eye ti won fun naa sori awon ologun wa.
Aya aare orile ede wa ko wi pe:
I whole-heartedly dedicate the award presented to me by the Belgian Deputy Prime Minister & Minister of Foreign & European Affairs, Minister Didier Reynders at the African women’s forum on “Women’s Role in global security” to the Nigerian Military men and women who have lost their lives and those at the war front battling to restore peace in the North East .
Fun eyin ti e o ba mo, Aya are je okan gboogi ninu eni ti o se idanilekoo ni aaye naa nibi ti opolopo awon iyawo aare orile ede alawo dudu wa.
E tun le ka eda iroyin yi ni ede geesi lori: http:/http://babayorubaonthebroadcast.blogspot.com.ng/2016/10/aisha-buhari-is-at-it-again-see-what.html/

Ki le ri so nipa re, e so si isale yii

Wednesday, 19 October 2016

E jowo e ka oro yii dele ni o. Omo Yoruba e dide, oju ko ma gbodo tiwa. e jowo e kun mi lowo lati doju ti GOOGLE.




Leta mi si gbogbo omo Yoruba lati owo Kolawole Azeez Baba Yoruba

Omo kootu oojire, awon agba lo bo won ni boju ko ba ti eyin igbeti oju ko ni ti eko. Ete awo ohun ni erin ogberi. Bi oro yi se dun mi to ni ko je kin roju raaye fi ami si ori oro yii. E bami gbaa bee

Akoko mo dupe lowo gbogbo eyin ti e maa n bami se abewo si ori oju ewe ayelujaraa mi. Owo te fi n ra data ko ni tan, ero ibanisoro yin ko ni sonu, ero komputa yin ko ni ko arun buruku (virus) depodepo pe yoo baje. Eto mi kan lo ma fe bo sonu lati owo google, sugbon google ko le so eto mi naa nu laisi owo eyin omo Yoruba nibe

Akoko idojuti nla gbaa ni fun wa nigba ti alase ati oludari FACEBOOK wa si orile ede Naijiria ti o si fi enu re so wi pe ede ti ohun feran ju ni ede Hausa nipa eyi oun yoo si ri daju wi pe yoo wo ori facebook. Bi ere bi ere ede Hausa ma de ori facebook looto ni kete ti arakunrin naa de ilu re. Ko si si awon olori wa kankan to ja tabi sapa ki ede Yoruba le de ori facebook

Bakan naa ti e o ba gbagbe awon Hausa ma ni ikanni tiwon lori BBC, Iyen BBC HAUSA. O seni laaanu wi pe Yoruba o raaye lori BBC, awon agbagba si dake won de n wo wa niran.

Ni ona keji, ni odun yii ti baba mi Alhaji Kolawole Lateef (Gbada) to se fiimu Atori lo si ile mimo meka, o pade omo ile larubawa kan loun to si so fun pe ede ti awon feran ju ni orile ede Naijiria ni ede Hausa. Nigba ti baba mi so oro naa fun mi, inu mi baje. mo tun mu iyen naa mora

Ni ona keta, okan ninu oju ewe ti mo ti maa n se akojo iroyin mi tii se naij.com, iyalenu lo je fun mi nibe nigba ti mo ba ede hausa pade lori oju ewe naa, mo gbinyanju lati ko leta ranse siwon pe ki won fi ede Yoruba kun sugbon mi o ri esi kankan gba. Haaa, oro yi dun mi gan, pelu pe ile Yoruba ni olu ile ise naa si wa.

Ewo eyin eniyan mi, gbogbo eleyii ko dun mi oo, eyi to dun mi ju ni egbin oniyoro ti GOOGLE fi kan mi. mo ti fe koko mu mora nipa pe kin dogbon si oro naa, sugbon owe awon agba meta kan lo gun mi ni kese ti mo fi ni mi o ni peyinda.
1. Ma fi oko mi se ona, ojo kan la n koo
2. Mi o le wa ku kan, ki ri oye ile baba re je
3. Owo ara eni la fi n tun iwa owo eni se.

Kini GOOGLE se fun mi
Sebi gbogbo yin le mo pe buloogi ni oju ewe mi yii je, ni eyi to je wi pe bi ero ba se po to ti won wo oju ewe kan ni won yoo se tete fun e ni anfaani lati polowo to. ipolowo yii ni won yoo ma fi san owo fun e. Osu mefa lo maa fi wa lori buloogi ki google to fun e ni AdSense pelu pe ero ti yoo ma wo buloogi re yoo po. Ohun ti awon eya yoku fi osu mefa se. Omo Kolawole pelu iranlowo yin mo fi osu kan se. Nibi ti gbogbo aye ti n gboriyin fun omo yi, oro naa ya google lenu, won fun mi ni AdSense laaarin osu kan. A ku oriire ni awon ore mi kimi. Lojiji ni GOOGLE gbe ara kan yo si mi won ni O SENI LAAANU PE EDE TI MO N LO LORI BULOOGI MI KIISE EDE TI AWON FOWO SI.
Eyi ni ohun ti google wi:
 

Your AdSense application status
Thank you for your interest in Google AdSense. Unfortunately, after reviewing your application, we're unable to accept you into AdSense at this time.
We did not approve your application for the reasons listed below.



  • Unsupported Language: We've found that the majority of your site’s content is in a language that we do not currently support. Right now, we're only able to offer language support and ad targeting for the languages listed in this help article. If you manage or own another site in one of our supported languages, feel free to resubmit your application as described below. While we look forward to supporting your language, we don't yet have a date as to when AdSense will be available for you. If you'd like to stay up-to-date with the languages that we support, please feel free to check back with us at the above link

  • Haa ara mi bu maso, inu mi baje, okan mi po ruru. mo wa ni kini mo le se. Mo da bi ogbon mo se idasile buloogi miran lati tu nnkan ti mo ko ni ede Yoruba si ede geesi. Sugbon eri okan ati orisun Yoruba ni kin ma se bee wi pe kin gbinyanju lati tera mo ede Yoruba kiko naa boya nigba ti awon ero ti o n woo ba po si daadaa google yoo le fowo si ede Yoruba gege bi ede kaakiri aye.

    Aaye yi ni oro naa ti kan yin, e jowo e bami kun gbogbo buloogi to ba je elede Yoruba lowo ki won le ni eero to po lori buloogi won ki google ma le fi eto wa dun wa mo.
    Mo dupe pupo lowo yin leekan si fun aduro ti yin paapaa julo lori ale mode mi nipa odun olojo ile ife. Laaarin wakiti marundinlogun eniyan 300 lo ti ye buloogi mi woo. E TE SIWAJU NIPA EYI KI A LE JE EDE ITEWOGBA KAAKIRI AYE KI GOOGLE MA LE FI ETO WA DUN WA OOOOO.

    E jowo, kini ero tiyin nipa ohun ti mo so sile yii, e je ka gbo.
    e ma fi esi yin si ori facebook ooo, isale alemode (post) yii ni ki e fi esi yin si

    Temi ni tiyin ni tooto
    Kolawole Azeez Baba Yoruba (facebook)
     {08030627995} (Whatsapp)
    Alase ati oludari ile ise Kolazad Group of Company
    Mi o ni gbagbe lati kii yin wi pe GBAYIIIIIIIII bi e se n fesi si oro mi

    Tuesday, 18 October 2016

    OÒNI ILE IFÈ DÉ ADÉ ARÈ FÚN ÌGBÀ ÀKÓKÓ. KINI N JÉ ADÉ ARÈ?


    I
    OÒNI ILE IFÈ Oba Adéyeyè Enitàn Ògúnwùsì Òjájá 1 dé Adé Are fún ìgbà àkókó.
    Gégé bí ó se máà n wáyé ní ododún osù kewàá odún 2016 ni wón se odún Olójó odún yìí ní ilé IFÈ. Odún yìí ní wón fi n sàmi àti ayeye àyájó ojó tí Odùduà wo ilé IFÈ.
    Adé tí Odùduà dé wo ilé IFÈ nígbà náà ni wón pè ní Adé Arè. Èèkan lódún ni oòni máa n dé Adé yìí, ìyen lásìkò ayeye odún Olójó.
    Láti ìgbà tí Oba Enitàn ti gorí apèrè, èyí ní odún Olójó àkókó tí wón yóò se, tí wón yóò sì ní ànfààní láti dé Adé Arè.
    Àlàyé lékùnréré n bò lójó iwájú nípa Adé Arè yìí, sùgbón èyí ni àwon àwòrán díè láti ibi ayeye náà.
    Oba Enitàn n kí àwon ará ilú

    Àwon ará ilú n kí Oba

    Oba Enitàn síjú fún àwon èèyàn


    Oòni n wúre fún Ilú



    A kí gbogbo omo Odùduà pé E kú Odún oooo
    Oba Enitàn Ògúnwùsì Òjájá 1 Adé a pé lórí, bàtà á pé lésé.
    .
    .
    .
    .E ti ro pe mo ti gbagbe Gbayiiiiii mi

    Sunday, 16 October 2016

    BÀBÁ YORÙBÁ tún yo pèlú àrà tuntun. E gbée yèwò.


    Èyin olólùfé BÀBÁ YORÙBÁ, a kí gbogbo yín wí pé e kú ìfé àti ìfomo ènìyàn se. Lágbára Olórun àdáwólé yín yóò ma yorí sí rere.

    Lára ònà tí a fé lò láti jé kí èyin olólùfé lè túbò gbádùn wa síwájú síi, ètò méta la ti là kalè fún ìgbádùn èyin ènìyàn wa. Èyí ni bí àwon ètò náà se lo;

    Òsè àkókó nínú osù: ìtàn àròso; nínú abala yìí la óò ti máa mú orísìírísìí ìtàn wá fún yin.

    Òsè kejì nínú osù: ìdánilékòó; ní abala yìí la óò ti máa dá ara wa lékòó nípa isé owó kan tàbí bí wón se n se nnkan kan

    Òsè keta nínú osù: E gbée yèwò; ní ààye yí ni a óò ti jo jíròrò lórí àkòrí kan láti mo ìwòye sí wa ní pàre

    Òsè tó gbèyìn osù: Njé o mò tàbí Kàyééfì; níbè la óò ti máa se àgbéyèwò àwon nnkan mérìíyìírí rí.

    Àyí padà yí yóò bèrè láti osù tó n bò, Sùgbón sá o, èyí kò dí ìròyìn gbogbo ìgbà wa lówó, àlékun àti àfikún lásán ni.

    Ní ìparí, a ro èyin olólùfé wa láti polówó isé, ojà tàbí òwò yín àti láti máa báwa ra ojà tàbí dòwòpò pèlú àwon tí ó n polówó lórí ìkànnì yí.

    Tèmi ni tiyín ní tòótó.
    Kóláwole Azeez (BÀBÁ YORÙBÁ)
    Mi ò ní gbàgbé láti so wí pé Gbayiiiiii

    Dókítà tó sì jé Alàgbà ìjo àti akékòó pàdé ikú òjijì ní ibi tó ti n gba àdúrà fún aláìsàn. Ohun tó pa á yóò yà yín lénu


    Akékòó ètò ìlera tó wà ní Èédégbèta lébùrù (500L) kú nígbà tí ó n gba àdúrà fún aláìsàn
    Olóògbé Victor David Egbe tó wà ní Èédégbèta lébùrù tó n kékòó nípa ètò ìsègùn òyìnbó àti ìse abe ní ilé èkó Ifáfitì ìpínlè Benue (Benue State University) ni ìròyìn so wí pé ó sà dédé subú lulè tó sì kú nígbà tí ó n gba àdúrà fún aláìsàn akegbé rè tó lo se àbèwò sí ní ilé ìwòsàn.
    Olóògbé náà je alàgbà àti olùdarí fún ìjo Campus Witness Church ní ilé iwé re. Gege bii adarí ìjo àti ajíhìnrere, ó lo be omo ìjo kan tó wà nílé ìwòsàn wò, níbí tí wón ti n gba àdúrà ni Egbe ti subú lulè tó sì gba ibè dágbére fáyé láì dúró gba ìtójú kankan.
    Èyí ní àwòrán Victor ní ibi tó ti n gba àdúrà
    Lágbára Olórun irú èyí kò ní kù Léyìn mó fún ebí olóògbé n.
    Irú rè kò dè ní jé ìpín enìkan kan wa.
    Gbayii fun gbogbo etó bá rí AMIN SE

    Saturday, 15 October 2016

    Haaa, Èyin Mùsùlùmí sé bí e o se máa wòran rèé. Òrò yí léwu oo



    Haaa, èyin Mùsùlùmí e gbó sé báyìí ni ànóbì Muhammad se ní kí e maa se se Ashura àti Taashura.Ìyàlénu nla gbáà ni fún mí nígbà tí mo rí ìròyìn yí ní naij.com, èyí ló mú mi fon rere re káyé wí pé sé báyìí ni ànóbì Muhammad ní ká máa se ìsìn yín.
    Ní ojó kesàn-án osù kewàá odun 2016 àti ojó kewàá osù kewàá odun 2016 tí ó bósì deede ojó kesàn-án àti ojó kewàá osù kìn-ín-ní odún 143 ti àwon Mùsùlùmí tí wón sì fi samì sí Ashura àti Taashura nípa ààwè, ìyàlénu lo jé wí pé bí àwon ijo shia káàkiri àgbáyé se n se ojó náà nínú ìjo tiwon yàtò. Níse ni àwon n fi orísìírísìí nnkan olóró gba èjè lára ara won. Ìwà yí kò yo omodé tàbí àgbà inú ìjo náà sílè. Wón ní àwon se èyí ní ìrántí Hussain omo Ali, tíí se omo omo Ànóbì Muhammad, nígbà tí omo náà kú sí ojú ogun Karbala ní odún 61AH tó sì bó sí àyájó ojó Ashura. E wo bí wón se n se ní ojó náà;

    Omo kékeré tó n gé ara rè

    Àgbàlagbà tó n gé omodé

    Òdó tó n gé ara won

    Àgbàlagbà tó n gé ara won

    Àwon omodé sí arawon

    Ohun tó wá se pabanbarì níbè ni pé tí wón bá se ayeye yìí tán won yóò wá tún sètò dókítà tí yóò tún se ìtójú won



    E gbó èyin Mùsùlùmí sé bórò se rí rèé, e làwá lóye
    ÈyinÀlùfáà, e báwa dá sí òrò yí o
    Láì pe yìí ni àwon Mùsùlùmí Kaduna, Kano, Sokoto àti àwon ilè Hausa gbé ogun ti àwon Shia tó wà ní ilú won. Wón dáná sun ilé, ilé ìwé àti ilé kéwu àwon Shia náà bákan náà wón sì pa lára won.
    Gbayii fún gbogbo Mùsùlùmí òdodo