propeller

Propellerads

Monday, 3 October 2016

Haaaa, Eyin osere ori itage, e dide ke jigiri si oro baba yii. iru eleyi koni sele siyin o.

Gbaju gbaja ni Alagba Tunde Alabi je laaarin awon osere ori itage orile ede Naijiria.
O seni laanu wi pe lowo lowo yii ti a n ko iroyin yii jo, baba naa wa ni ile iwosan gbogbo ti ipinle eko (Lagos state general hospital) ni bi ti o ti n gba itoju si ese re.
Aarun jejere lo koko bere pelu baba naa titi to fi se akoba fun ese re. Awon onisegun si n so wi pe bi won ko ba jara mo oro ilera osere yii, o seese ki baba naa padanu ohun to ju ese re lo.

Okan ninu awon ore re (Julius Paul) se alaye wi pe; O seese ki won ge ese otun baba naa laipe ti ko ba si iranwo kokan fun baba naa nipa owo. Idi ni ti awon fi n ke gbajare si gbogbo awon alaanu lorile ede agbaye lati ran Alagba Tunde Alabi lowo.
Ailaso lorun paka, o to apero fun gbogbo mariwo. Ki awon osere ori itage naa si ran okan ninu elegbe won lowo.

Fun iranlowo lati owo yin:

Oruko:                 TUNDE OBAFEMI ALABI
 Ile ifowopamo:  UNITY BANK PLC
No. :                     0005647181

Lagbara Olorun aisan ti ko gboogun ko ni se kooge wa ooo
Gbayiiiiii fun gbogbo oninu ire


No comments:

Post a Comment