O̩jó̩ burúkú ès̩ù gbomi mu ni
o̩jó̩ Àìkú, o̩jó̩ ke̩tàlélógún, os̩ù ke̩wàá, 2016 jé̩ fún àwo̩n
olólùfé̩ e̩gbé̩ agbá bó̩ò̩lù Manchester United nígbà tí e̩gbé̩ agbá
bó̩ò̩lù Chelsea lùwó̩n ní pàs̩án 4 – 0. Ohun tó wà pani lé̩rìn-ín
níbè̩ ni pé ò̩pò̩lo̩pò̩ nínú àwo̩n oló̩lùfé̩ Man U ni wó̩n fi ìkanra
ò̩rò̩ náà mó̩ àwo̩n ará ilé wo̩n. È̩yin náà e̩ ye̩ ohun tí Muritala
Habeeb Herdemola so̩ sí ojúìwé (facebook) rè̩ fún àpe̩e̩re̩ irú ìkanra
àwo̩n o̩mo̩ Man U: (Muritala ko̩ó̩ ní
èdè gè̩é̩sì àwa la tú u sí èdè Yorùbá)
* O̩KO̩ ÀTI ÌYÀWÓ,
WÓ̩N DÁKÉ̩ RÓ̩RÓ̩ NÍ ORÍ ÌBÙSÙN*
Ìyàwó ń
ronú:
Kílódé tí kò
bámi sò̩rò̩?
S̩é ó ń ronú
obìnrin míràn ni?
Àbí ó ti ń
rí e̩lòmíràn ni?
S̩é mi ò re̩wà
lójú rè̩ mó̩ ni?
S̩é mo ti wá
di è̩gbin lójú rè̩ ni?
S̩é ó ti ń kórìírà
àwo̩n ìs̩aralógé mi ni?
Kílódé tí kò
fi bámi sò̩rò̩ láti ìgbà tó ti dé?
Mo mò̩ pé ìyá
rè̩ kò fé̩ràn mi, bóyá wó̩n sì ti ń pèsè ìyàwó míràn fún un ni?
S̩é bí mo s̩e
máa wá di ìyá ń dágbé rèé…?
Olúwa, jò̩wó̩
bámi dáàbò bo ìgbéyàwó mi.
KÍNI Ó Ń BÍ
I NÍNÚ?
Lé̩è̩kan náà
ni ó fi ìgboyà bèèrè ò̩rò̩ ló̩wó̩ o̩ko̩ rè̩, “Olólùfé̩ mi, Kílodé
tí ó fi bámi sò̩rò̩? Kíni mo s̩e fún e̩ tí mo fi tó̩ sí irú ìwà yìí?”
omi sì ń jábó̩ lójú rè̩.
O̩ko̩ rè̩ yíjù
padà sì i, ojú rè̩ pó̩n, ìbínú súyo̩ lójú rè̩, ó sì fi ìbínù
dá ìyàwó rè̩ lóhùn wí pé *”Báwo ni Chelsea lásán làsàn s̩e máa
na Man U ní 4 – 0 tí a sì ní agbá bó̩ò̩lù bíi Rashford, Pogba àti
Ibramovic lórí pápá?”*
Tó bá jé̩ è̩yin
ni arábìnrin náà kí le̩ máa s̩e
Tó bé̩è̩ ju
bé̩è̩ lo̩, orílonís̩e lò̩rò̩ bó̩ò̩lù àfe̩sè̩gbá, Man U e̩ gbìnyànjú
ju bé̩è̩ lo̩ ní ìgbà míràn
Gbayii fun gbogbo olólùfé̩ bó̩ò̩lù afesegba
E̩ te̩ ààyé
yí láti ka ò̩rò̩ yí ní èdè gè̩é̩sì: http://babayorubaonthebroadcast.blogspot.com.ng/2016/10/see-what-chelsea-and-man-u-cause-to.html
No comments:
Post a Comment