Thursday, 6 October 2016
Ile ejo dojuti Stella Oodua. E wo ibi ti oro iya yi tun ja si
Eni ti olopa mu, toni oun o gba horo, be oun o gba koroIbi to ba wu ko gba, ko sa ti de ile ejo.
Iya Aafin Stella Oodua ni minisita fun oko ofurufu ni igba isejoba Aare Goodluck Jonathan. Ajere iwa ibaje ina kuna tabi sise owo ilu basubasu si mo arabirin naa lori, ni ajo ti o n moju to iwa odaran ati ise owo ilu kumo kumo (EFCC) ba ni ki iya naa ko fo ko niso. Awon agbofiro naa gbiyanju lati mi iya naa, sugbon a fi biri ni iya naa gba ile ejo lo gege bi owe Yoruba to so wi pe eni to ba to ni gba la n sa ba. Iya naa ro ioe ejo wi pe ki won pase pe ki won ma jee ki EFCC tabi agbofiro tabi ajo kankan fi oro wa ohun lenu wo ta wa idi oun tabi ba oun sejo. Awijare iya naa ni wi pe oro naa niise pelu ogbon oselu ati lati ba oun loruko je. SUGBO eyi ni abajade ile ejo.
Hmmm, o seni laaanu wi pe ibi ti iya naa foju si ona o gba ibe. Ile ejo ko fun iya naa wi pe o di dandan ki iya naa yoju si gbogbo ajo tabi agbofiro to ba pee lati fi oro wa lenu wo tabi lati baa sejo.
Adajo Abdu Kafarati da ejo naa ni ojo kerin, osu kewa odun 2016 wi pe, o faramo awijare EFCC pe o se pataki fun Stella lati yoju si ajo kajo to ba pe e nitori aabo ara re. Eyi ni ohun ti Adajo Kafarati da lejo:
Kii se ibani loruko je ni fun eniyan ti won ba pe ko wa wi tenu re, kii si se ite eto omo eniyan loju mole bi kii se aabo fun eni ti won fi esun kan ki o ba le we ara re mo kuro nibi iye meji esun ti won fi kan an.Nitori idi eyi ko seese fun ile ejo yii lati ko fun ajo tabi agbofiro kan lati se ise won nipa sise iwadi iwo Stella Oodua. Eyi yoo je anfaani funbe lati we arabre mo kuro nibi esun ti won ba fi kan e naa. Ni pa idi eyi ile ejo yii da ejo re nu won si pase pe ki awon agbofiro maa ba ise won lo nipa iwadi naa ki iwo naa si yoju siwon fun iforowanilenu wo tabi iwadi ti won ba fe se.
Pelu idajo yii Stella Oodua si n tenu mo pe oro naua lowo kan oselu ninu
Egbo se looto ni pe ogbon oselu ni EFCC n da lori Stella Oodua
Leyin gbogbo iroyin la o ma ki yin pe Gbayii
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment