Àjó̩ tí ó ń mójú tó ètò ìdìbò ní ìpínlè̩ Ògùn ti kéde àbájáde ètò ìdìbò tó wáyé ní O̩jó̩ Ke̩jo̩, Os̩ù ke̩wàá, o̩dún 2016 sí àwo̩n ìjo̩ba ìbílè̩ Ogún (20) àti àwo̩n agbègbè ìdàgbàsókè mé̩tàdínlógójì(37) tó wà ní ìpínlè̩ náà.
Ìyáàfin Risikat Ògúnfé̩mi tó jé̩ alága àjo elétò ìdìbò náà kéde èsì ìdìbò náà wí pé, egbé tó wà lórí àlééfà ló̩wó̩ (APC) ló jáwé olúborí sí ipò alága ní gbogbo àwo̩n ìjo̩ba ìbílè̩ ogún (20) àti àwo̩n agbègbè ìdàgbàsókè mé̩tàdìnlógójì (37) tó wà ní ìpínlè̩ ògùn.
Bákan náà, E̩gbé̩ APC tún mú ò̩ó̩dúnrúnlélé̩rìndínláàdó̩ta
(347) nínú ò̩ó̩dúnrúnlélóókàndínláàdó̩ta (349) ipò káńsélò̩
tó wà ní ìpínlè̩ Ògùn nígbà tí e̩gbé̩ òs̩èlú UPN mú méjì (2)
tí e̩gbé̩ òs̩èlú PDP sì mú e̩yo̩ kan soso.
E̩gbé̩ Akòròyìn orílè̩ èdè Nàìjíríà jábò̩ ìròyìn
wí pé; e̩gbé̩ òs̩èlú mé̩tàdínlógún (17) ló kópa nínú ètò ìdìbò
náà.
Alága àjo elétò ìdìbò wá so pé, e̩ni tí àbájáde
ìdìbò náà kò bá té̩ ló̩rùn kó gbé e̩jó̩ náà lo̩ sí ò̩dò̩ àjo̩
tó ń rísí kùdìè̩ kudie tó wà nínú ìdìbò tí wo̩n yóò gbé kalè̩
láìpé̩.
E̩ gbó̩ kíni èrò yín nípa bí e̩gbé̩ APC s̩e mú
gbogbo ìjo̩ba ìbílè̩ ní ìpínlè̩ Ògùn.
O̩mo̩ ògùn! Is̩é̩ yá ooooo!!!
Gbayii fún gbogbo o̩mo̩ ògùn
No comments:
Post a Comment