A dúpé̩ oo, wó̩n ti ń dá àwo̩̩n o̩mo̩bìnrin
s̩íbó̩ò̩gì sílè̩ oooo.
Ìròyìn yàjóyàjó tó ń tè̩ wá ló̩wó̩ ló̩wó̩ báyìí
ń so̩ wí pé; àwo̩n o̩mo̩ ilé è̩kó̩ síbó̩ò̩gì tí àwo̩̩n e̩gbé̩ alákatakítí
Boko Haramu kó ni wó̩n ti ń dá wo̩n sílè̩.
Ìròyìn náà fi yéwa wí pé mó̩kànlélógún(21) nínú
àwo̩̩n o̩mo̩ náà ni wó̩n ti dá sílè̩ ni òwúrò̩ kùtùkùtù o̩jó̩
ojó̩bò̩, o̩jó̩ ke̩tàlá os̩ù ke̩wàá o̩dún 2016.
Tí a kò bá gbàgbé, àwo̩̩n alákatakítí náà kó àwo̩̩n
o̩mo̩ o̩mo̩bìnrin tó tó bíi igba (200) nínú o̩gbà ilé ìwé wo̩n ní ìpínlè̩
Bornu
ní o̩dún 2014. Ìròyín fi yé wa wí pé díè̩ nínú àwo̩̩n o̩mo̩ náà
ti kú tí à̀wo̩̩n alákatakítí náà sì di àwo̩̩n tó kù mú sí
ìkáwó̩ wo̩n
Gé̩gé̩ bí òs̩ìs̩é̩ ìjo̩ba kan ti bá BBC Africa sò̩rò̩,
ó so wí pé; àwo̩̩n alákatakítí náà kó àwo̩̩n mó̩kànlélógún(21)
nínú àwo̩̩n o̩mo̩bìnrin sí agbègbè Banki ní ìpínlè̩ Borno, níbè̩
ni àwo̩̩n o̩mo̩ ogun orílè̩ èdè Nàìjíríà ti wá fi o̩kò̩ òfurufú
agbérapá wá kó wo̩n.
Àwo̩̩n kan
nínú àwo̩̩n ìyá àwo̩̩n o̩mo̩bìnrin náà wá ke sí olórí orílè̩ èdè
yí fún ìrànló̩wó̩ láti bá àwo̩̩n gba àwo̩n tó ku nínú àwo̩̩n o̩mo̩
náà.
Láìpé yìí ni àwo̩̩n Boko Haram pe olórí orílè̩ èdè
yí Muhammad Buhari lórí è̩ro̩ ìbánisò̩rò̩ láti so̩ fún ìjo̩ba àpapò̩
wí pé kí wó̩n fi àwo̩̩n ake̩gbé̩ àwo̩̩n tí ó wà lé̩wo̩n sílè̩ kí àwo̩̩n
tó dá àwo̩̩n o̩mo̩ náà sílè̩, ohun tí kò wá yé wa ni pé bóyá ìjo̩ba
àpapò ti fi àwo̩̩n ake̩gbé̩ wo̩n náà sílè̩ ni àwo̩̩n náà s̩e fi àwo̩̩n
o̩mo̩bìnrin náà sílè̩.
S̩ùgbó̩n óo, àìpé̩ yìí ni àwo̩̩n alákatakítí yìí
tún ju àdó olóró kan
nínú o̩kò̩ ayó̩ké̩lé̩ tí ó sì mú è̩mí ènìyàn mé̩jo̩ lo̩.
A kí gbogbo o̩mo̩ Nàìjíríà kú orí ire, a sì ń gbàá
ládùrá wí pé kí O̩ló̩run jé̩ kí wó̩n lè fi àwo̩̩n tó kù sílè̩ òo.
Gbayii fún olórí orílè̩ èdè wa
Gbayii fún àwo̩̩n ológun orílè̩ èdè wa
Gbayii fún àwo̩̩n má jè̩é̩ kó bàjé̩
Gbayii fún gbogbo o̩mo̩ orílè̩ èdè Nàìjìríà lápapò̩
No comments:
Post a Comment