Òsèré fíìmù tó sì jé olùdámòràn fún ìjoba ipinle Kwara nípa òrò àsà àti ìse ògbéni Fémi Adébáyò ya gbogbo àwon olólùfé rè lénu lánàá nígbà tí ìròyìn pé ó se ìgbéyàwó tó won létí. Ìròyìn náà jáde láti owó alámòjúto ilé isé Fémi Adébáyò (Bíódún Adégòkè) pé, ògá àwon ti se ìgbéyàwó ìdákónkó pèlú arábìrin kan tí orúko rè n jé Omotáyò Maimunat Sanusi ni ojó kesàn-án osù kewàá odun 2016.
Fémi àti Ìyàwó rè tuntun
Èyí ni ohun tí wón ko jade:Fémi Adébáyò ti se ìdàpo mímó pèlú olúlùfé rè Omotáyò Sanusi pèlú ayeye ìdákónkó pèlú àwon ebí ìdílé méjèèjì àti àwon òré asúmóni julo. Èyí rí béè nítorí béè nítorí báa se fée nìuyen. Àti wí pé gégé bí eni tó ti ní ìyàwó télè rí, tí ìyàwó mi kò sì tíì ní, mo nílò láti dáàbò bòó ní gbogbo ònà. E jòwó, a bèbè fún àgbóyé èyin ará, òré àti olúlùfé. Àdúrà àti àtìleyìn la nílò. E seun. Pèlú ìfowósì aláse.
Àdúrà wa ni pé kí Olórun fi èrè tó pò si.
Mi ò ní lo láì kí i pé Gbayiiiiii.
No comments:
Post a Comment