propeller

Propellerads

Tuesday, 4 October 2016

Idi re to fi se pataki fun e lati le SO, KO ati KA ede Yoruba. Idi keta, ikarun ati kefa yoo ya o lenu, yoo si se e ni anfaani



EdeYoruba je ede abinibi fun awa eya Yoruba. Bo tile je wi pe ede naa ti n di ede ajoji laaarin won lode oni. Sugbon awon agba bo, won ni, 'teni yeni tekisa ni taatan, elenu rirun lo si ni amu iya re.'
O seni laaanu wi pe bi ede Yoruba se rewa to ni gbogbo ona (asa, ise, ede ati iwa) awon ti won ni ede naa ti ko iyan re kere laaarin won, pabanbari ni wi pe, awon ajoji feran ede naa ju awon to nii lo.

 Sugbon oloju ko ni la oju re sile ki nnkan buruku gbon si i. Idi niyi yi a fi fe toka si awon anfaani kan to wa ninu siso, kiko ati kika ede Yoruba.
1. Yoo fun o ni anfaani lati ni imo tokun nipa agbegbe re
2. Ironu re ati iwadi re yoo le gunrege, yoo si je pelu irorun
3.Yoo tun fi e han gege bi eni pataki ati eni otun lawujo ibi ti gbogbo awon eniyan ba ti je wi pe ede miran ni won yan laayo.
4. Yoo bu olakun e gege bii eni ti o mo ohun to n se ni agbegbe re.
5. Yoo mu idanilekoo rorun fun oluko ati akekoo, gege bi ede abinibi ati ede agbegbe eni
6. Yoo tun je koo mo eyi ti yoo se o ni anfaani ninu oro, bi apeere eniyan ti ko ba gbo ede Yoruba ko nimo pataki awon gbolohun isale yii

Lagbara Olorun oju koni ti e, inira o kere o tobi ko ni kan iwo to ka apileko yi. Eyi to ti n dun ninu oro re ko ni baje, eyi to ku die kaato ki Oba oke ba o so di irorun.
Gbayii fun gbogbo eni to ba n gbe ede Yoruba ga.

No comments:

Post a Comment