Agbè fó̩ba kìí jè̩bi gé̩gé̩ bí òwe àwo̩n àgbà. S̩ís̩e
is̩é̩ O̩ló̩pàá (agbófinró) yálà ló̩kùnrin tàbí obìnrin, ó ko̩já
ohun tí ò̩pò̩lopò̩ ará ìlú ń fojú wò. O̩kùnrin tóń sun rárà fún
o̩kùnrin e̩gbé̩ rè̩, ako̩ is̩é̩ ló ń s̩e. Gé̩gé̩ bí a ti rí i ní orí
ojú ewé ayélujára naij.com, wó̩n s̩e àfihàn àwo̩n àwòrán kan tí ó
ń júwe orís̩ìírís̩ìí is̩é̩ tí àwo̩n o̩ló̩pàá ń s̩e láàárín ìlú.
E̩ jé̩ ka sún sí ìsàlè̩ láti ye̩ àwo̩n àwòrán mé̩tàdínlógún yìí
wò láti mo pàtàkì is̩é̩ o̩ló̩pàá;
1. Nígbà míràn is̩é̩ wa pè̩lú kí á máa
di agbòòrùn mú fún àwo̩n olówó, a s̩e eléyìí nítorí ìfé̩ tí a
ní sí àwo̩n ará ìlú àti nítorí owó
2. Àwo̩n òyìnbó òkè òkun náà máa ń je̩ àǹfàní
nínú is̩é̩ gbígbé agbòòrún dání wa náà tàbí nípa rírán wa nís̩é̩.
3. Nígbà míràn è̩wè̩ a máa ń gbé àpamó̩wó̩ fún
àwo̩n aya olórí àti alás̩e̩ tàbí aya alé̩nuló̩rò̩ láàárín ìlú,
tí e bá jé̩ olówó olórò láàárín ìlú e̩ jé̩ ká mò̩ yín bóyá a
lè ran è̩yin náà ló̩wó̩
4. Kí o̩ló̩pàá re̩wà̩ jé̩ ohun ìwúrí fún wa nínú
is̩é̩ o̩ló̩pàá, èyí jé̩ ò̩kan lára ohun tí ó máa mú is̩é̩ náà
wu ni
5. Ìgbà míràn, a máa ń ló̩ alábòsí tàbí arúfin
lá́ra kó tó di wí pé a óò fi o̩wó̩ òfin gbá a mú
6. Kò sí e̩ni tí kìírè̩, ó lè rè̩ wá lé̩nu is̩é̩,
ó s̩e pàtàkì fún wa láti sùn bí kò tilè̩ ju wákàtí kan lo̩.
7. Ní ìgbà míràn orí èèyàn jé̩ ohun tí a máa ń
bá pàdé lé̩yìn o̩kò̩ àwo̩n ènìyàn, s̩ùgbó̩n kìí bàwá lé̩rù
8. Àrà wà ló̩wó̩ wa tí a máa ń dá tí yóò yà yín
lé̩nu púpò̩, àgààgà lásìkò is̩é̩, e̩ má lo̩ fojú kéré agbára wa
9. Ó s̩eés̩e ká gbéná wojú ara wa, lára ohun tí a kó̩
mó̩ is̩é ni, kò sí ojú s̩àájú, kìí s̩e ohun ìtìjú rárá, ènìyàn
e̩lé̩ran ara làwa náà̩
10. Àlùbami ni a máa ń lu e̩lòmíràn, kìí s̩e nítorí
ìkórìra s̩ùgbó̩n lára ò̩nà láti lè fi ìdí òfin múlè̩ ni
11. Nígbà tí a bá so̩ wí pé òfin mú e̩, s̩ùgbó̩n tí
o gbìnyànjú láti s̩e bí e̩ni wí pé o gbó̩n, àwa náà máa ní láti
gbé e̩ gé̩gé̩ b́í ìkókó tí kò gbó̩, kílódé tóò s̩e kúkú s̩e bí
àgbàlagbà
12. A máa dúró tí ò̩daràn láti ya àwòrán, bótilè̩
jé̩ wí pé kò wù wá, s̩ùgbó̩n a ní láti s̩e é, lára is̩é̩ wa ni
13. Tí àwa mé̩ta bá dòyì ká e̩, má s̩e s̩e bí alágbára,
nítorí ó s̩eés̩e ká lo ohun ìjà o̩wó̩ wa, ìgbè̩yìn rè̩ sì lè jásí
ohun tí o kò fé̩
14. ́Lára adùn is̩é̩ wa ni wí pé àwa àti olórí
orílè̩̀ èdè máa ń jo̩ dá ò̩wé̩kè̩ nígbà míràn
15. Tí a bá pò̩ wo̩ àdúgbò́ yín báyìí, e̩ má s̩e
fòyà, àrà náà la fi dá.
16. A tún máa n gba àdúrà pè̩lu yín nígbà tí a bá n báa yin gbé àpamo̩wó̩ dání gé̩gé̩ bíi olùrànló̩wó̩
17. Ju gbogbo rè̩ lo̩, e̩ má s̩e gbàgbé wí pé Ò̩RÉ̩
YÍN NI O̩LÓ̩PÀÁ
Pè̩lu gbogbo ohun tí a kà sókè yí, njé̩ o lè s̩e is̩é̩ O̩ló̩pàá
Gbayii fún gbogbo O̩ló̩pàá
Pè̩lu gbogbo ohun tí a kà sókè yí, njé̩ o lè s̩e is̩é̩ O̩ló̩pàá
Gbayii fún gbogbo O̩ló̩pàá
No comments:
Post a Comment