Haaa, èyin Mùsùlùmí e gbó sé báyìí ni ànóbì Muhammad se ní kí e maa se se Ashura àti Taashura.Ìyàlénu nla gbáà ni fún mí nígbà tí mo rí ìròyìn yí ní naij.com, èyí ló mú mi fon rere re káyé wí pé sé báyìí ni ànóbì Muhammad ní ká máa se ìsìn yín.
Ní ojó kesàn-án osù kewàá odun 2016 àti ojó kewàá osù kewàá odun 2016 tí ó bósì deede ojó kesàn-án àti ojó kewàá osù kìn-ín-ní odún 143 ti àwon Mùsùlùmí tí wón sì fi samì sí Ashura àti Taashura nípa ààwè, ìyàlénu lo jé wí pé bí àwon ijo shia káàkiri àgbáyé se n se ojó náà nínú ìjo tiwon yàtò. Níse ni àwon n fi orísìírísìí nnkan olóró gba èjè lára ara won. Ìwà yí kò yo omodé tàbí àgbà inú ìjo náà sílè. Wón ní àwon se èyí ní ìrántí Hussain omo Ali, tíí se omo omo Ànóbì Muhammad, nígbà tí omo náà kú sí ojú ogun Karbala ní odún 61AH tó sì bó sí àyájó ojó Ashura. E wo bí wón se n se ní ojó náà;
Omo kékeré tó n gé ara rè
Àgbàlagbà tó n gé omodé
Òdó tó n gé ara won
Àgbàlagbà tó n gé ara won
Àwon omodé sí arawon
Ohun tó wá se pabanbarì níbè ni pé tí wón bá se ayeye yìí tán won yóò wá tún sètò dókítà tí yóò tún se ìtójú won
E gbó èyin Mùsùlùmí sé bórò se rí rèé, e làwá lóye
ÈyinÀlùfáà, e báwa dá sí òrò yí oLáì pe yìí ni àwon Mùsùlùmí Kaduna, Kano, Sokoto àti àwon ilè Hausa gbé ogun ti àwon Shia tó wà ní ilú won. Wón dáná sun ilé, ilé ìwé àti ilé kéwu àwon Shia náà bákan náà wón sì pa lára won.
Gbayii fún gbogbo Mùsùlùmí òdodo
No comments:
Post a Comment