Wednesday, 5 October 2016
Eyi ni okan lara isoro ti o n ja orile ede Naijiria; awon oluko lo faa
EPE AWON OLUKO LO N JA ORILE EDE NAIJIRIA
Bi ko si ti oluko tani a ko ba ma pe ni adajo
Bi ko si ti oluko tani a ko ba ma pe ni dokita
Bi ko si ti oluko tani a ko ba ma pe ni onimo ero
Oluko lo ko wa bi a o se se ohun gbogbo
Abi ta lo gbe imo re wa lati orun
Laise wi pe enikan lo ko o.
Eni ba pe ti oluko bawo
Haaa, oro epe ko aye onitoun yoo polukuru musu ni.
Sebi oluko kan lo ko olori orile ede yin lona kan abi omiran
E ma simi gbo o
Kii se eko iwe nikan ni mo n toka si oo
Gbogbo irufe eko towu ti ki baa je, yala imo iwe ni tabi ti kewu, eko ise ni tabi eko iwuwasi.
OLUKO NI OLUKO NJE.
E waa gbo o, orile ede ki orile ede, ilu ki ilu, abule ki abule, aye kaaye, enikeni, eniyan ki eniyan, omo komo, olori kolori, omo ijo ki omo ijo, agbegbe ki agbegbe ti won ba ti ko iyan Oluko kere. Haaaaaa, haaaaaa, haaaaaaa ilu naa ko le roju, aaye naa ko le raye, eku o le ke bi eku, bee eye ko le ke bi eye, koda omo eniyan naa ko le se bi omo eniyan mo. Nitori bi eni to fi oju oloore gun igi ni tabi ka so wi pe bii alaimoore eda ni iru iwa bee. Eyi to buru ju ninu ohun taa le pe iwa yi ni ODALE
ORILE EDE NAIJIRIA N DALE AWON OLUKO.
Oluko lo ye ki aponle wa fun ju, sugbon awon ni a yeye ju
Oluko lo ye ki owo oya re po ju, sugbon awon ni owo won kere
Oluko lo ye ki a toju ju, sugbon awon ni a n fiya je ju
Oluko lo ye ki a se adura fun ju, sugbon awon ni a n bu ju
Haaaa, orile ede Naijiria e ro nu e pa iwa owo yin da si oluko ki ilu yii ba le toro
Abo mi re oo
Adura mi ni wi pe lagbara oba mi ti enikan ko riri, gbogbo oluko ko ni to omo olomo ki o sori ire ki omo tiwon wa sori buruku oo.
E jowo e bami se adura fun awon oluko
Gbayii fun gbogbo eni ba mo riri oluko re
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment