1. Ǹjé̩ o mò̩ pé 6236 ni iye e̩se̩ tó wà nínú Kùránì
mímó̩?2. Wó̩n dárúko̩ Kùránì nínú Kùránì fúnra rè̩ fún
ìgbà 70
3. Nínú orí wo ni wó̩n ti s̩e àlàyé bí wó̩n s̩e dá
o̩mo̩ ènìyàn nínú Kùránì? Kó sí iyè méjì nínú Sura Hijr e̩se̩ 26
ni
4. Mo mò̩ pé ò̩pò̩ ènìyàn máa rò wí pé Suratu
Ikhlas ni, s̩ùgbó̩n rárá o, Suratul Kausar ni sura tó kéré jùló̩ nínú
ìwé mímó̩
5. Bí Suratu Kausar s̩e wá kéré tó, ò̩rò̩ 42 ló wà
nínú rè̩
6. Ò̩pò̩lo̩pò̩ lè má mò̩ wí pé Alif bé̩è̩ni Alif ا ni áràfí tí wó̩n lò jù nínú Kùránì
alápò̩nlé
8. Sura kan
wà nínú Kùránì tó jé̩ wí pé nínú gbogbo e̩se̩ rè̩ ni wó̩n ti dárúko̩
O̩ló̩run, sura náà ni Suratul Mujadala
9. Sura wo ni wó̩n fi ‘Dal’ gbè̩yìn gbogbo e̩se̩ rè̩? Fún
àwo̩n tí kò mò̩, Suratul Iklas ni
10. Òmíràn tún rèé, surah wo ni arafi ‘Ra’ gbè̩yìn
gbogbo e̩se̩ rè̩? E̩ má ròó jìnà Suratul Kausar ni
11. Ó ye̩ ké̩e̩ ti gbó̩ pé Suratu Yaseen ni o̩kàn Al
Kùránì
12. Suratul Fatia ni wó̩n sì pè ní Ìyá Al Kùránì
13. Ò̩pò̩lo̩pò̩ ènìyàn lè má mò̩ pé è̩è̩mejì ni
wó̩n so̩ Suratul Fatia kalè̩ (ní Meka àti Medina)
14. Mo rò wí pé e̩ mò̩ pé kìí s̩e suratul Fatia nìkan
ló bè̩rè̩ pè̩lú Al-Hamdulillahi. A tún ní àwo̩n surah mé̩rin míràn,
àwo̩n náà ni: Suratul Anaam, Kahf, Saba & Fatir
15. Ó yani lé̩nu wí pé nínú gbogbo sura inú Kùránì
ni áràfí faf ف ti hàn, àyààfi nínú suratu fatia nìkan.
S̩ùgbó̩n níbi tí O̩ló̩run tóbi dé, kàkà kó hàn nínú àwo̩n e̩se̩
inú rè̩, ara orúko̩ sura náà ló ti hàn. Bóyá ohun tí à ń so̩ kòyé,
nínú gbogbo àwo̩n sura tó wà nínú Kùránì, gbogbo àwo̩n sura yí ni áràfi
náà hàn nínú e̩se̩ wo̩n kan tàbí òmíràn, s̩ùgbó̩n nínú suratu
fatia láti òkè délè̩, Faf kò hàn nínú rè̩ rárá. Dípò kó hàn nínú
àwo̩n e̩se̩ náà, ara orúko̩ súrà náà ló ti hàn. Allahu ló tóbi ju
gbogbo títóbi lo̩.
Ohun kóhun tí mo bá so̩ tó jé̩ òtító̩ tó sì s̩e wá
ní àǹfàání, e̩ gbà wí pé pè̩lú àánú àti àtìle̩yìn O̩ló̩run
ni, s̩ùgbó̩n èyí tó bá ku díè̩ káàtó, láti o̩wó̩ mi ló ti wá.
Allah nìkan ló ní ìmò̩ nípa gbogbo nnkan, kí ó sì s̩e àforij́ì àwo̩n
às̩ìs̩e wa.
Olúwa pó̩n wa lé, kí o sì dáàbò bòwá gé̩gé̩ bí
o s̩e s̩e fún Al Kùránì Mímó̩.
È̩dà àlè̩móde yìí wà ní ède gè̩é̩sì ni: http://babayorubaonthebroadcast.blogspot.com.ng/2016/10/15-wonderful-fact-about-holy-quran-i.html?m=1
No comments:
Post a Comment